Èsì rèé tí Femi Adesina fọ́ ní ìdáhùn sì ìròyìn pé Buhari lóun fẹ yan ẹni tí yóò rọ́pò rẹ ní 2023

Aworan aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti fesi si iroyin to gbode pe Aarẹ ni oun fẹ kawọn Gomina faaye gba oun lati yan ẹni ti yoo rọpo rẹ lọdun 2023.

Femi Adesina agbẹnusọ aarẹ lo fesi yi to si ni ko si ootọ ninu ọrọ naa.

Adesina ninu apilẹkọ kan to fi sita lẹyin abẹwo aarẹ si orile-ede Spain ni awọn ọmọ Naijiria kan nifẹ si ki wọn maa da awuyewuye silẹ nitori naa Aarẹ ko sọ ohunkohun to niṣe pẹlu ''zoning, consensus tabi fifi eeyan rọpo aarẹ''

Kini Aare Buhari sọ?

Ninu ọrọ rẹ, Adesina sọ pe nkan ti Aarẹ sọ fun awọn Gomina APC lasiko ipade to se ko to lọ si Spain ni pe ki wọn jẹ ki ero wọn papọ ki ẹgbẹ ba a le yan ẹni to kajuẹ lasiko idibo abẹnu wọn.

O ni ko pẹ lẹyin ipade yi lawọn gbera lọ ṣi irinajo ni Spain.

O ni awọn ọmọ Naijiria maa n da awuyewuye silẹ nibi ti ko ba ti si ni,

Ati pe awọn kan wa to ṣe pe bi wọn ko ba ri ọrọ ti wọn yoo ma ran lẹnu, wọn a maa da ọrọ silẹ lati le fi ri nkan sọ.

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Aarẹ lẹtọ lati yan ẹni ti yoo rọpo rẹ, ko si ohun to buru nibẹ

Bi Adesina ṣe n sọ tiẹ lẹgbẹ kan pe Aarẹ ko loun yoo yan ẹlomiran ti yoo rọpọ rẹ, niṣe lawọn ẹgbẹ kan to n jẹ Buhari Media Organisation n sọ pe ko sohun to buru ti aarẹ ba fẹ yan ẹni ti yoo rọpo rẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ yi fi sita lorukọ alaga Niyi Akinsiju ati akọwe rẹ́, Cassidy Madueke wọn ni 'anfaani to pọ lo wa nibi ki ẹni to wa nipo yan ẹni ti yoo rọpo rẹ''

Wọn ni aarẹ Buhari ko ṣe nkan to buru ati pe awọn rọ awọn Gomina APC pe ki wọn gbaruku ti aarẹ lati jẹ ko yan ẹni ti yoo rọpo rẹ nitori yoo ṣe anfani fun orileede Naijiria lọpọ

Aworan aarẹ Buhari ati awọn Gomina APC

Oríṣun àwòrán, Laureta Onochie

Lafikun, ẹgbẹ yi ni itẹsiwaju yoo le ba iṣejọba bi aarẹ ba yan ẹni ti yoo rọpo rẹ ati pe kii ṣe orileede Naijiria nikan ni iru nkan bayi ti n waye.

Ọrọ ti wọn yi yatọ si eleyi tawọn lẹgbẹlẹgbẹ lọgbalọgbamii ati awọn onwoye oṣeluni Nairia n sọ pe aarẹ fẹ fi ijọba gaba lelẹ ni Naijiria ni.

Ni paapa awọn to tako ọrọ yi nio yẹ ki aarẹ sọ pe oun fẹ iranwọ awọn Gomina lati yan oludije ni dipo bo ṣe ni ẹni ti yoo rọpo rẹ lẹyin saa rẹ.

Wọn ni ohun ti eletyyi tunmọ si ni pe aarẹ kobikita boya awọn eeyan dibo yan ẹni ti yoo ṣe ijọba lẹyin rẹ bi kii ṣe pe ifẹ inu rẹ lo fẹ gbe le awọn ọmọ Naijiria lori.