Wo àwọn olùdíje ẹgbẹ́ APC tí yóò fi ohun gbogbo lù Atiku lálùbami lọ́dún 2023 - Olóyè APC

Aworan idamọ APC ati Atiku

Ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Farouk Aliyu ti fi igboya sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu awọn ko bẹru oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Atiku Abubakar rara.

O ni awọn ni odidi eeyan marun to dangajia to tun koju osuwọn lati fi ẹyin Atiku gbolẹ daadaa ninu idibo ọdun 2023. Họnọrebu Farouk Aliyu to jẹ ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC n sọ ọrọ yii lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo lori amohunmaworan Channels.

Gẹgẹ bo ṣe n sọrọ lọwọ pe itumọ ti awọn ọmọ Naijiria fun ẹbẹ aarẹ Buhari lati yan ọmọ oye ko dara to si ni ifẹ araalu naa ni aarẹ n ja fun, Farouk ni o da oun loju pe ẹni ti ero to pọ ju ninu ẹgbẹ ba mu naa ni yoo jẹ oludije awọn.

Ki ni Atiku ni to lee dẹru ba alatako rẹ?

Farouk Aliyu gba pe lootọ, Atiku kii ṣe eeyan kan to yẹ ki awọn foju kere tabi fi ọwọ rọ sẹhin paapaa nitori bo ṣe jẹ gbajumọ ni orilẹede yii.

Amọ sibẹ sibẹ o ni “aimọye oludije wa to lee ja Atiku sẹhin patapata.

Awọ naa tun ni gbẹ to wa lori oye, a o ni joko tẹtẹrẹ ki wọn maa gbe iru awọn nkan bayii gba ẹgbẹ wa kọja lai ṣe nkankan. O wa darukọ awọn to da a loju gidi pe ko si bi Atiku ṣe fẹ le to, wọn lee sọ ọ di rirọ ti wọn yoo si di aarẹ bi wọn ba ba a figagbaga.

Awọn ni:

  • Oloye ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu
  • Minisita eto irina tẹlẹ Rotimi Amaechi
  • Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo
  • Minisita abẹle fun eto ẹkọ, Emeka Nwajiuba

“A ni ju eeyan marun lọ to lee gbo ewuro soju Atiku Abubakar a si maa ṣiṣẹ wa daadaa labẹle ki awọn ọmọ Naijira le dibo fun APC tori iṣẹ taa ti ṣe.

Bakan naa lo ni ko ni ṣe pẹlu ẹya tabi igun ibikibi ti ẹni naa ba ti wa lorilẹede Naijiria o amọ koko ni pe ẹni ti awọn ọmọ Naijiria yoo fẹ ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, aarẹ Buhari gẹgẹ bii adari ẹgbẹ APC n wa ẹni to dantọ ni.

“Emi naa si jẹ ọkan lara awọn to n wa ẹni to dantọ. ẹni to lee na Atiku, ko ni lati wa lati Ariwa tabi Guusu, o da mi loju pe ẹgbẹ wa yoo ṣe nkan to tọ”.