Ago mẹ́jọ si mẹ́wàá alẹ́ ni Adedoyin àti ọmọ rẹ wá sí ilé ìtura ni ọjọ́ tí Timothy Adegoke dé sí ilé itura - Adedeji Adesola

Ramon Adedoyin

"Mọ rí Adedoyin, ọmọ rẹ̀ àti àwọn adari "manager" ile ìtura níbi tí wọn ti ń ṣe ipade

Osisẹ Hilton Hotel Honour, Adesola Adedeji ti o fun oloogbe Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ni kọkọrọ yara ni Dokita fun Rahmon, Rahmon Adedoyin ati Ọmọ rẹ, Roheem Adedoyin wa ni ile ìtura ni ọjọ ti Timothy Adegoke de si ile ìtura naa.

Adesola ni o sọ eleyi nigba ti agbejoro Femi Falana fi ọrọ wa lẹnu ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ni ọjọ Aje.

Adedoyin ni ile ẹjọ

Bawo ni irinajo Adedoyin ati ọmọ rẹ ṣe jẹ lọjọ naa?

Oṣiṣẹ ile itura naa to jẹri ni ile ẹjọ Adesola ni Dokitaa Rahmon Adedoyin wa si ile ìtura naa ni bi ago mẹjọ ale ni ọjọ karun-un oṣu kokanla ọdun 2021 lati wa wo alafia awọn osise. Ó tẹ̀siwaju pe nigba ti o di ago mẹwa alẹ ojo naa, ọmọ Adedoyin Roheem Adedoyin naa wa si niluu ile ìtura Hilton Hotel Honour. "lẹyin ti a gba oloogbe Timothy Adegoke de si ile ìtura naa, Ọga agba ile ìtura wa, Dr Rahman Adedoyin wa si niluu ile ìtura Hilton Hotel Honour, wọn awọn waa alafia awa osise. "Ko pe ni ọmọ wọn Roheem Adedoyin naa wa ti mọ ri pelu awon manager nibi ti won ti se Ipadẹ ṣugbọn mi o mọ nnkan ti wọn sọ"