Wole Oluyede ADC Ekiti: Ibi tó yẹ kí Ekiti wà kọ́ ni eléyìí; Ẹ lẹ́ẹ ṣe ọ̀nà, a ò ríbi tó jásí o, àmọ́ tí mo bá di gómìnà...
Oludije si ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Ekiti, Dokita Oluwole Oluyede ti bu ẹnu atẹ lu awọn oludije mii to n sọ pe awọn ni ki ara Ekiti dibo yan.
O ṣalaye idi ti ipo tirẹ ṣe wulo bo ba di gomina ipinlẹ naa ati nkan ti yoo ṣe.
"Ẹ ma jẹ ka maa tan ara wa pe ọfẹ ni eto ilera ba de, ijọba naa lo maa sọ pe ibi la ti le mu owo jade".
Bakan naa ni Oluyede ṣalaye pe ki awọn ara ipinlẹ ma reti owo kankan to n bọ lati olu ilu orilẹede yii, Abuja.
dipo eyi, o ni ki wọn gbagbe ninu ara wọn ati nkan ti wọn le ṣe ni ipinlẹ Ekiti.
Bakan naa lo ni ko si nkan to buru ninu Baba Isalẹ ninu oṣelu amọ alafẹyinti to to Ọlọrun ba ko si.
