Zama Zama South Africa gold mine: Níbi tí góòlù bá ti wa, ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣàn níbẹ̀ - Ìrírí awakùsà rèé
Ikọ ọtẹlẹmuyẹ BBC tun ti ṣagbejade iwadii ijinlẹ kan eyi to ni ṣe pẹlu ọna ti wọn n gba wa ilẹ lọna aitọ lorilẹede South Africa.
Fidio naa ṣafihan bi awọn arinrinajo ṣe n fi ẹmi ara wọn ati gbogbo ohun ti wọn ni wewu lati lee wa ọna atijẹ.
Ṣe ni wọn n gbe ninu ilẹ ti wọn ti n wa goolu eyi to ti di apati.
Ojoojumọ ni wọn n lọ si ibi iṣẹ amọ wọn ko ni imọ boya wọn yoo pada sile wọn laaye.
Ìṣẹ́ lo sọ wọn di ẹni to n gbe labẹ ilẹ lati maa lọ wa goolu.
Ninu eyi naa ni ijọba ti n fi panpẹ ofin mu awọn kan fun wiwa goolu lọna aitọ ti awọn mii lara wọn si n gba ibẹ ku.
"Ẹru maa n ba iyawo àti awọn ọmọ mi lọpọ igba tori ewu to wa ninu iṣẹ wa".
Arakunrin kan sọ iriri rẹ bi gende ọkunrin mẹrin to gbe ibọn lọwọ ṣe ṣe ikọlu sii labẹ ilẹ naa.
O ni ilẹ tun maa n ya bo awọn, amọ igbe aye ati iṣẹ ti wọn yan laayo ree.
Orukọ ti wọn n pe ara wọn ni "awa Zama Zama".

