Àwòrán ‘Portrait’ Queen Elizabeth ti jáde láti ṣayẹyẹ ọdún 70 gẹ́gẹ́ bí Ọba Ilẹ̀ UK

Ọbabinrin Elisabẹti

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi, Queen Elizabeth ti jade ṣaaju ayajọ ayẹyẹ ọdun aadọrin to gun ori oye.

Ayaworan Ranald Mackechnie lo ya fọto naa ni ibẹrẹ ọdun yii ni Victoria Vestibule to wa ni Windsor Castle.

Awọn to ṣeto ayẹyẹ naa ni ohun meremere lorisirisi ni yoo waye lasiko ayẹyẹ naa.

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni yoo bọsi igboro lati ṣe ayẹyẹ aadọrin ọdun ti ọbabinrin naa gori oye. Ọjọ mẹrin ni wọn yoo fi ṣe ayẹyẹ naa, eleyii ti yoo bẹrẹ ni Ọjọbọ, ti yoo si pari ni Ọjọ Isinmi.

Bí àwòrán Ọbabìnrin náà ṣe rí...

Ọbabinrin Elizabẹti

Oríṣun àwòrán, RANALD MACKECHNIE

Ọbabinrin Elizabeth naa ti wọn ya aworan rẹ joko ni ori aga ni ẹgbẹ ferese

Ọbabinrin naa ri bi ẹni ti ọkan rẹ balẹ.

Afin ti Ọbabinrin naa ti wa fun ọpọ ọdun diẹ bayii ni wọn ti ya aworan naa

Bi eto ayẹyẹ naa yoo ṣe lọ niyii

Atẹjade

Ninu ọrọ Obabinrin naa si awọn eniyan rẹ ni o ti dupẹ lọwọ gbogbo eniyan fun aduroti oun pẹlu ipinnu pe oun yoo lo asiko yii lati fi woye bi oun ṣe lo aadọrin ọdun lori oye.

• Ọjọbọ ni eto naa yoo bẹrẹ pẹlu ayẹyẹ ni igboro pẹlu awọ orisirisi ti awọn eniyan yoo wọ kaakiri igboro pẹlu awọn soja lori ẹṣin lorisirisi.

Idile Ọbabinrin

Oríṣun àwòrán, Reuters

• Ni irọlẹ Ọjọbọ ni wọn yoo tan ina to le ni ẹgbẹrun mẹta kaakiri Ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi ayẹyẹ fun Ọbabinrin naa.

• Ọjọ Ẹti ni wọn yoo lọ si St Paul’s Cathedral lati lo ṣe isin idupẹ, ti wẹjẹ-wẹmu yoo si waye ni irọlẹ ọjọ naa.

• Wẹjẹ wẹmu tẹsiwaju kaakiri ilu ati igboro Ilẹ Gẹẹsi pẹlu ounjẹ lorisirisi fun awọn eniyan.