Àwọn gómìnà Àríwá nínú APC kéde pé ẹkùn gúúsù làwọn faramọ́ pé kí ààrẹ ti jáde

Awọn gomina to wa lati apa oke ọya ninu ẹgbẹ oselu APC ti kede pe ẹkun guusu Naijiria ni awọn fara mọ pe ki ipo aarẹ pada si.
Nitori idi eyi, awọn gomina apap oke ọya naa ti wa nahun kesi awọn oludije fun ipo aarẹ to wa lati ẹkun naa pe ki wọn yọwọ, yọsẹ kuro ninu ilakaka wọn lati dije du ipo aarẹ.
Alẹ ọjọ Satide ni awọn gomina apa Ariwa naa kede bẹẹ lẹyin ipade wọn to waye nilu Abuja.
Lara awọn gomina to peju sibi ipade naa ni Aminu Bello Masari tipinlẹ Katsina; Abubakar Sani Bello ti Niger; Abdullahi Sule ti Nasarawa; Ọjọgbọn Umara Zulum ti Borno; Nasir El-Rufai lati Kaduna; Muhammad Yahaya lati Gombe ati Bello Matawalle ti ipinlẹ Zamfara State.
Awọn gomina yoku ni Simon Lalong tipinlẹ Plateau; Dokita Umar Ganduje ti Kano; Abubakar Atiku Bagudu ti Kebbi ati gomina ana nipinlẹ Sokoto, Aliyu Wamakko.
Atẹjade ti awọn gomina naa fisita lẹyin ipade wọn ọhun ni awọn se agbeyẹwo ipe aarẹ sawọn gomina atawọn eeyan miran ti ọrọ oselu gberu lati ri daju eeyan to dantọ ni ẹgbẹ oselu APC fa kalẹ lati dije fun ipo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Northern APC Governors’ Forum
“Lẹyin ijiroro wa, a panupọ pe lẹyin ọdun mẹjọ ti aarẹ Muhammadu Buhari ti lo lori aleefa, ẹkun guusu Naijiria lo kan bnayi lati fa oludije fun ipo aarẹ kalẹ ninu ẹgbẹ oselu APC.
Iwa iyi ati iwuri ni igbesẹ naa yo jẹ fun ẹgbẹ oselu APC eyi ti ko ni nnkan kan se pẹlu ipinnu yowu ti ẹgbẹ oselu miran ko baa se.
A wa n dabaaa fun aarẹ Buhari pe ẹkun guusu Naijiria la gbọdọ doju kọ ninu ilakaka ẹgbẹ oselu APC lati fa ọmọ oye fun ipo aarẹ.”
Atẹjade naa wa n rọ awọn oludije fun ipo aarẹ lati ẹkun ariwa Naijiria pe ki wọn yọwọ kuro ninu idije naa.
Awọn gomina ẹkun ariwa salaye pe wọn n rọ awọn oludije ọhun lati yọwọ nitori ifẹ orilẹede wọn, ki awọn oludije lati ẹkun guusu nikan si kopa ninu idibo abẹnu ẹgbẹ APC ti yoo waye lọjọ Aje.












