Ibrahim Magu, Alága àjọ EFCC yóò gbé ìwé àwíjàre rẹ̀ tọ ìgbìmọ̀ olùwádìí Aàrẹ wò lónìí

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, others

Alaga ajọ EFCC to n rọọkun nile lọwọ bayii, Ibrahim Magu yoo tun farahan niwaju igbimọ oluwadii ti aarẹ gbe kalẹ lati gbe awijare rẹ kalẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Aarẹ Buhari gbe igbimọ naa kalẹ labẹ akoso onidajọ Ayọ Salami.

Iṣẹ wọn ni lati wadii iṣẹ ati iṣe Magu gẹgẹ bi alaga ajọ EFCC ati ajọ EFCC gan an pẹlu.

Eyi ko ṣeyin bi agbẹjọro agba fun orilẹ-ede Naijiria to tun jẹ minisita feto idajọ, Abubakar Malami, SAN ṣe kọwe ifisun si Aarẹ.

Amofin agba, Malami fi awọn ẹsun agbọ-gbọnti kan Magu ninu eyi ti a ti ri ẹsun ṣiṣe owo baṣubaṣu, jiji awọn ẹru ti wọn ri gba ko ti wọn si n ta wọn fawọn ọrẹ ati ojulumọ wọn.

Ni Ọjọbọ lo yẹ ko kọkọ ti gbe awijare rẹ kalẹ ṣugbọn ko lee ṣe bẹẹ nitori gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin abẹle ṣe sọ, awọn ọmọ igbimọ naa ko yọju sii rara.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Wo ìdí tí wọ́n fi dá Alága àjọ EFCC Ibrahim Magu sílẹ̀

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe, wọn ti da alaga ajọ EFCC, Ibrahim Magu silẹ.

Agbẹjọro rẹ, Toyin Ojaomo fi to ileeṣẹ iroyin abẹle kan leti pe Ọgbẹni Magu ko si ni ahamọ mọ.

Ibrahim Magu gba idasilẹ rẹ lẹyin to lo ọjọ mẹwaa ni ahamọ igbimọ oluwadi ti aarẹ gbe kalẹ lati wadi ẹsun kotọ ati iwa magomago ti agbẹjọro agba lorilẹede Naijira, Amofin Abubakar Malami fi kan an.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ ṣalaye wi pe awọn ko mọ ohunkohun nipa ahamọ ti wọn fi alaga ajọ EFCC ti arẹ Buhari yọ nipo naa.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adesina ṣalaye pe ko si ẹni to tii fi ẹsun ọdaran kan Magu, iwadii lasan lo n waye lori bi nnkan ṣe n lọ si ni ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC.