Covid Update: Ṣé orílẹ̀èdè míì wà l'Áfíríkà tó ń lo rọ́bọ́ọ̀tì ní pápákọ̀ òfurufú bíi ti Nàìjíríà?

Rọ́bọ́ọ̀tì ní pápákọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Nigeria Defence News/Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Naijiria ti di orilẹede akọkọ ni Afirika ti yo maa lo ẹrọ abaniṣiṣẹ rọbọọti ni papakọ ofurufu gẹgẹ bi ẹka iroyin ileeṣẹ ologun Naijiria ṣe sọ ọ.

Nibayi awọn ẹrọ abaniṣiṣẹ rọbọọti yii ti wa nilẹ digbi wọn si ti duro deede lati maa ṣe ayẹwo gbogbo arinrinajo ni papakọ ofurufu Naijiria lati asiko ajakalẹ arun COVID-19 yii.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin ileeṣẹ ologun Naijiria ṣe fi sita loju opo Twitter wọn nibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo awọn rọbọọti naa pe orilẹede Naijiria ni orilẹede akọkọ nilẹ Afirika ti yoo ra rọbọọti ti o lee gbe gbogbo iroyin nipa arinrinajo jade ti yoo si maa ṣe ayẹwo wọn ẹnu ọna gbọngan abajade papakọ ofurufu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Rọ́bọ́ọ̀tì ní pápákọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Nigeria Defence News

Nibi ti wọn f'ogun awọn irinṣẹ ti Naijiria ra yii gbari de, wọn tun kede pe "bi orilẹede Afirika kankan ba wa to ti gbe iru igbesẹ lilo rọbọọti fun iṣẹ ni papakọ ofuru wọn, ẹ jẹ ka mọ. A n duro tọkan tọkan.

Kia lawọn ọmọ Naijiria ti han wọn kaun ṣugbọn koko awọn ọrọ ti wọn n sọ ẹka iroyin ileeṣẹ ologun Naijiria fi han pe lootọ bi awọn orilẹede miran l'Afirika tilẹ n lo awọn mọsiini abani ṣiṣẹ yii, kii ṣe ni papakọ ofurufu bii ti Naijiria

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ko pẹ lawọn ọmọ Naijiria mii naa tu sita pẹlu lati mẹnu le ọrọ awọn ohun elo iranwọ tuntun yii.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ologun jẹ ko di mimọ pe iyatọ gedegbe wa laarin iṣẹ ni papakọ ofurufu ati ibomiran. Lilo rọbọọti ni gbogbo papakọ ofurufu ti wọn n gba rinrinajo lọ ilẹ okere ni Naijiria ni wọn n sọ tori naa bi awọn eeyan o ba lee kan sara si ijọba Naijiria fun iṣẹ takun takun, ki wọn ma fa ibọn yọ o tọrọ ba ti kan ohun daradara nipa Naijiria.