Qasem Soleimani: Iran ni Trump gbọdọ̀ jẹ́jọ́ lórí ikú ọ̀gágun tí Amerika pa

Ọmọ ilẹ Iran kan mu aworan ọgagun Soleimani dani lọjọ Kẹrin osu Kini ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Qasem Soleimani padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu ado oloro Drone ti Amẹrika yin lu

Orileede Iran ti fi iwe ipẹjọ sita pe ki awọn agbofinro mu aarẹ Amẹrika Donald Trump lori iku ọgagun ilẹ wọn kan Qasem Soleimani ti Amẹrika pa.

Losu kini ọdun yi ni ilẹ Amẹrika fi ado oloro pa Soleimani ni Iraq.

Olupẹjọ ni Tehran Ali Alqasimehr sọ pe ọgbẹni Trump ati awọn marundinlogoji mii n koju ẹsun isekupani ti awọn si ti kan si ileesẹ ọlọpaa lagbaye Interpol lati bawọn mu wọn.

Ṣugbọn Interpol ti sọ pe ohun ko ni siju wo iwe ti Iran kọ.

Aṣoju orileede Amẹrika pataki si Iran sọ pe otubantẹ ni ọrọ ti Iran n sọ yi ati pe ko si ẹni ti yoo ka wọn kun.

Ọgagun Soleimani padanu ẹmi rẹ lẹba papakọ ofurufu Baghdad nigba ti awọn ọmọ ogun Amẹrika yin ado oloro Drone kan lu to si ṣeku pa.

Awọn eeyan Iran n dana sun asia ilẹ Amẹrika lati fi ẹhonu han si bi Amẹrika se pa ọgagun wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Iku ọgagun Soleimani mu ki Amẹrika ati Iran gbena woju ara wọn

Aarẹ Trump lo paṣẹ pé ki wọn ṣeku pa, nítori pe o ni pe ọgagun Soleimani lọwọ ninu iku awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ati pe o n gbimọọtẹ lati se ikọlu si Amẹrika.

Ilẹ Iran naa gbẹsan pẹlu bi wọn ti se yin ado oloro lu ibudo awọn ọmọ ogun Amẹrika to wa ni Iraq.

Ileeṣẹ iroyin Mehr sọ pe ọgbẹni Alqasimehr ni "Awọn eeyan mẹrindinlogoji lawọn ti ri wi pe wọn lọwọ ninu iṣekupani ọgagun Soleimani.

Wọn mojuto, bẹẹ si ni wọn kopa ti wọn si paṣẹ bi wọn se pa''

" Ninu wọn la ti ri awọn osisẹ ologun lati ilẹ Amẹrika ati awọn ilẹ miran ti ẹka idajọ wa si ti fi iwe asẹ ki wọn mu wọn sita koda a ti fi to Interpol leti''

Olupẹjọ agba naa sọ pe orukọ aarẹ Trump lo lewaju ti awọn yoo si gbe igbesẹ lati mu koda ko ti kuro lori alefa.