Iran plane crash: Ìfẹ̀hónúhàn ṣẹ́yọ lẹyìn tí Iran ní oun ló já bàálù Ukrain lulẹ̀

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ṣaaju ni orilẹ-ede Iran ti kọkọ sẹ pe, oun ko mọ ohun kohuin nipa bi baalu naa ṣe ja lulẹ

Ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Iran ti bẹrẹ ifẹhonuhan lẹyin ti ijọba orilẹ-ede naa sọ pe oun ṣeṣi ja baalu orilẹ-ede Ukrain bọ.

Awọn eeyan naa tun pe fun iwadii kikun ati iṣedajọ ododo fun gbogbo awọn to lọwọ ninu bi baalu ọhun ṣe ja, leyi to mu ẹmi eeyan mẹrindinlọgọsan an lọ.

Lara awọn to n pe fun iwadii yii ni aarẹ orilẹ-ede Ukrain, Volodymyr Zelensky ati adari ijọba orilẹ-ede Canada, Justin Trudeau.

Ninu ifẹhonuhan to n lọ lọwọ lorilẹ-ede Iran ni awọn eeyan ti n pe fun ikọwe-fiposilẹ olori to gaju lorilẹ-ede ọhun, Ayatollah Ali Khamenei.

Ọjọru ọsẹ yii ni baalu naa jabọ, lẹyin ti orilẹ-ede Iran ti kọkọ fi misaili ranṣe si ojuko ti awọn ọmọ ogun Amẹrika wa ni Iraq.

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Misaili naa jẹ esi si bi Amẹrika ṣe gbẹmi ọkan gboogi lara awọn ọgagun orilẹ-ede Iran, Qasem Soleimani ni Bagdad, lọjọ kẹta oṣu yii.

Àkọlé fídíò, Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Ṣaaju ni orilẹ-ede Iran ti kọkọ sẹ pe, oun ko mọ ohunkohuin nipa bi baalu naa ṣe ja lulẹ, ṣugbọn ni bayii, akara ti tu sepo.

Àkọlé fídíò, 'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

IranPlaneCrash: A kò mọ̀ọ́mọ̀ ju irínṣẹ́ ìbúgbàmù lu bàálù Ukrain tó já

Ọkọ baalu Ukrain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ogun orilẹ-ede Iran ti ni aṣiṣe o kọgbọn, awọn ṣe eṣiṣi ju irinṣẹ ibugbamu lu ọkọ bàálù Ukraine ti ọpọ ẹmi ti sofo.

Ileeṣẹ tẹlifisan orilẹ-ede lo fi iroyin naa sita to si ni ijọba ni gbogbo awn to wa nidi ọrọ naa ni wọn yoo fi jofin.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Ninu ọrọ naa, wọn fi hande pe ohun tawn ṣe yii aṣiṣe ẹda ni nigba tawọn ri i pe kọ baalu naa n fo sunmọ agbegbe kan to ṣe pataki si awọn ikọ alaabo ilẹ Iran.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Iran ti ṣaaju kọ iroyin to gbode kan pe irin ibugbamu ti Iran lo ja baalu naa lulẹ lba olu ilu orilẹ-ede naa, Tehran lọjọru ọsẹ.

Ṣugbọn ọrọ yii bẹrẹ si ni le sii nigba ti orilẹede Canada ati US sọ ọ gbangba pe awọn gbagbọ pe Iran lo yin nkan sinu afẹfẹ lati ja baalu naa.

Bi ọkọ baalu naa to gbe arinrinajo mẹrindinlọgọsan an ṣe ja lẹyin wakati perete ti Awọn ọmọogun Iran ko irinṣẹ ibugbamu wọn jade.

Iroyin taa gbọ ni pe orilẹ-ede Amẹrika sọ pe Iran ro pe ọkọ baalu ijagun ni wọn ro pe o jẹ gẹgẹ bi wọn ṣe n gbaradi lati ṣe ikọlu pada si Amẹrika.

Ẹ ma gbagbe pe ohun to jẹ kulẹ kulẹ ọrọ yii to bẹr rẹ ni asiko ti orile-ede Amẹrika ṣekupa olori ogun kan to lagbara ju lorilẹ-ede Iran iyẹn Soleimani.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'