Presidency: Kí ló dé tí Ààrẹ Buhari tún ń dá àwọn tó fúnrarẹ̀ yọ nípò pàdà

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fa iwe aṣẹ gbele ẹ ti wọn fun oludari agba ajọ ipese ina igberika lorilẹ-ede Naijiria, REA, Arabinrin Damilọla Ogunbiyi ya.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti minisita fun ọrọ ohun amuṣagbara, Sale Mamman ti paṣẹ pe ko lọ rọọkun nile.

Amọṣa, ileeṣẹ aarẹ ṣalaye lori pe wọn fa iwe naa ya lati lee fun laaye lati funra rẹ kọwe fipo silẹ ki o lee lọ gba ipo tuntun to ṣi silẹ fun un ni ajọ iṣọkan agbaye.

Igbesẹ yii mu ki ọpọlọpọ eeyan lorilẹ-ede Naijiria ati loke okun o bẹrẹ si ni kun lori aṣa rin siwaju yọdi-sẹyin ti ijọba yii ti gbe lori awọn iyannisipo awọn eeyan kan lati igba to ti de aleefa.

Diẹ ree lara awọn eeyan ti aarẹ ti da pada lẹyin ti wọn ti rọ wọn loye lati igba ti aarẹBuhari ti de ipo ni ọdun 2015:

Ọjọgbọn Suleiman Bogoro

Oríṣun àwòrán, Tetfund

Àkọlé àwòrán, Kí ló dé tí Ààrẹ Buhari tún ń dá àwọn tó fúnrarẹ̀ yọ nípò pàdà

Ọjọgbọn Suleiman Bogoro, akọwe agba ajọ iṣuna eto ẹkọ giga ni Naijiria, TETFUND:

Ni ọdun 2014 ni aarẹ ana, Goodluck Jonathan kọkọ yan an sipo ṣugbọn oṣu keji, ọdun 2016 ni ijọba aarẹ Buhari yọọ kuro nipo.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Ẹsun ti wọn fi kan Bogoro ti wọn fi yọ ọ nigba naa ni pe ọwọ rẹ ko mọ lori igba biliọnu naira kan ti ajọ naa gbe sita fun akanṣẹ iṣẹ ṣugbọn tawọn kan ṣe baṣubaṣu.

Ṣugbọn oṣu kinni, ọdun 2019 ni wọn to tun daa pada sipo naa.

Usman Yusuf

Oríṣun àwòrán, @NhisNg

Àkọlé àwòrán, Kí ló dé tí Ààrẹ Buhari tún ń dá àwọn tó fúnrarẹ̀ yọ nípò pàdà

Usman Yusuf, oludari agba ileeṣẹ adojutofo ilera, NHIS

Lẹyin ọpọlọpọ iwadii si awọn ẹsun iwa aṣemaṣe ti wọn fi kan an ni minisita feto ilera nigba naa, Ọjọgbọn Isaac Adewọle yọ Usman Yusuf nipo gẹgẹ bii akọwe agba ileeṣẹ adojutofo ilera, NHIS.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Amọṣa, lẹyin asiko diẹ ni ikede tun waye pe ijọba apapọ ti da a pada si ipo rẹ.

Abdulrasheed Maina

Oríṣun àwòrán, @abdulrashid_mai

Àkọlé àwòrán, Kí ló dé tí Ààrẹ Buhari tún ń dá àwọn tó fúnrarẹ̀ yọ nípò pàdà

Abdulrasheed Maina, ileeṣẹ owo ifẹyinti awọn ọlọpaa

Ni ọdun 2013 ni ajọ iṣẹ ijọba apapọ le Maina kuro nipo lẹyin aṣẹ ofiisi olori ẹka oṣiṣẹ ijọba lorilẹ-ede Naijiria.

Lara ẹsun ti wọn fi kan an nigba naa ni pe o sa lẹnu iṣẹ.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

Ẹsun ti wọn fi kan Maina nigba naa ni pe ọwọ rẹ ko mọ lori bi wọn ṣe lu biliọnu meji naira, owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ni ponpo.

Lẹyin iwadii ile aṣofin agba, pa aṣẹ iwe aṣẹ fun awọn agbofinro lati mu u jade ṣugbọn o na papa bora.

Àkọlé fídíò, LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé

Ni ọdun 2017 ni Maina ba tun wọle pada sẹnu iṣẹ ọba, koda ipo oludari kan ni ileeṣẹ ọrọ abẹle ni wọn da a pada si ki ariwo to sọ.

Ipada sipo rẹ gan an fa olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ ati olori ẹka oṣiṣẹ nigba naa, Winifred Oyo-Ita gbe'na woju ara wọn.

Lẹyin ọpọlọpọ ariwo ni aarẹ Buhari to ni ki wọn le e nipo ki wọn le ṣe iwadii rẹ bi o ti yẹ.