Ondo 2020: Tani ìgbìmọ̀ tó ń sàyẹ̀wò olùdíjẹ lábẹ́ APC nípínlẹ̀ Ondo yọ kúro gan-an?
Láìpẹ́ yìí ni ìròyìn kàn pé ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) tó ń ṣe àyẹ̀wò àwọn olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ náà sọ pé Segun Abraham ni kò kójó òṣùwọ̀n tó nínú àwọn tó ń díje nítori náà ni wan ṣe yọ.
Segun Abraham jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjìlá tó ń dije lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ APC tó sì ti gbá ìwé láti fi èrò rẹ̀ hàn pé, òun ṣetan láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ náà ti yóò wáye ní Ogúnjọ́, Oṣù Keje ọdún yìí.
Sùgbọ́n nínú ìfọ̀rọ̀wáni lẹ́nu wò ti BBC News Yoruba ṣe fún olùdíje náà, Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé títí di àsìkò yìí, ìgbìmọ̀ kò ti fi tó òun léti pé òun ni wọ́n yọ.
- Ẹ wo ọ̀nà tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ gbà san owó àwọn olùkọ́ iléèwé aládàni tí kò rówó oṣù gbà
- Ọlọ́pàá kọ́ lo pa olórí àwọn ''One Million Boys'' Ebila n'Ibadan- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Àwọn dókítà Eko bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lórí owó oṣù àti ètò adójútòfò fún ìtọ́jú coronavirus
- Wole Soyinka rèé láti kékeré
- Kí ló dé tí Igbákejì Gomina Ondo ní kí wọ́n yọ Abẹnugan Ilé Aṣòfin?
"Títí di àsìkò yìí mí ò ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ àyẹ̀wò pé èmì ni wọ́n yọ, tàbi ki wọ́n kọ lẹta nípa rẹ, wọ́n ni, wọ́n ni, ní mò ń gbọ́."
Àwọn tí wọ́n jọ díje ni Joseph Olusola Iji, Odimayo Okunjimi, Olayide Owolabi Adelami, Isaacs Duerimini Kekemeke, Olusola Oke Alex, lfeoluwa Olusola Oyedele àti Olajumoke Olubusola Anifowoshe.
Àwọn tó kù ni Awodeyi Akinsehinwa Akinola Colinus, Olubukola Adetula, Dr. Abraham Olusegun Michael, Gomina Rotimi Akeredolu ati Dokita Nathaniel Adojutelegan.









