Lazarus Chakwera: Ààrẹ orílẹ̀-èdè Malawi 'tó bá Ọlọ́run jiyàn'

Aarẹ Lazarus Chakwera

Oríṣun àwòrán, Reuters

Yoruba bọ, wọn ni iwa kii fi oniwa silẹ, bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede Malawi, Lazarus Chakwera lasiko to ba awọn eeyan orilẹ-ede naa sọrọ nípa isọkan lẹyin ti wọn búra fun tan.

Oṣu mẹtala ni orilẹ-ede naa fi pin yẹlẹ-yẹlẹ, nitori awuyewuye to waye lori esi idibo ọdun 2019, ile ẹjọ fagile esi idibo naa.

O sọ pe ko dara to lati kan ni àlá lai sisẹ to tọ.

O ni "asiko ti de fun wa lati ṣe tayọ àlá wa nikan."

"Gbogbo wa gbọdọ jí kuro loju orun, nitori pe asiko niyii lati mu ki àlá wa sẹ."

Iranṣẹ Ọlọrun ni Ọgbẹni Chakwera jẹ ni orilẹ-ede Malawi.

Ọdun 2013 ni ẹni ọdun marundinlaadọrin naa di olori ẹgbẹ oṣelu Malawi Congress Party, lai ni iriri kankan nipa oṣelu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijakadi pẹlu Ọlọrun

O di oloṣelu lẹyin ọdun mẹrinlelogun to ti jẹ oludari ijọ Assemblies of God. O jẹwọ pe ko rọrun fun oun nigba ti oun pinnu lati du ipo aarẹ lọdun 2014.

"Mo ni lati ba Ọlọrun jiyàn lori ọna ti mo gba pe o yatọ pupọ.

Sugbọn lẹyin ọpọlọpọ ijiroro," Ọlọrun sọ pe: mo n sọ isẹ ìranṣẹ rẹ di gbigbooroo, ki o le ṣe olùṣọ́ àgùntàn odidi orilẹ-ede."

O tun sọ ninu ifọrọwanilẹnu kan lọdun 2017 pe, lasiko ijiroro pẹlu Ọlọrun ni oun tun ka iwe Ẹ́ksódù ninu Bibeli, nibi ti Ọlọrun ti farahan Mose, to si sọ fun un pe ko dari awọn ọmọ Ísrẹ́lì jade kuro ni Egypti.

Oludamọran rẹ, Sean Kampondeni sọ fun BBC pe, eyi lo fihan pe adari le mojuto igbe aye ẹ̀mí ati ti ara, awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn kii ṣe pe o fẹ ṣe isakoso Malawi ni ilana ẹ̀kọ́ Bibeli.

Awọn ara orilẹede Malawi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Aarẹ gbagbọ pe isejọba orilẹ-ede jẹ nkan ti Ọlọrun lọwọ si, lati le mu ilọsiwaju ba awujọ, ati ọmọniyan.

Ọgbẹni Kampondeni tun sọ pe" O gbagbọ pe isejọba ti wo lulẹ ni Malawi, ti ko si ṣe ojuse yii, lati ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin. O si ti yọnda ara rẹ lati ṣe ojuṣe naa."

Ọmọ oniwaasu ati ajinhinrere ni Ọgbẹni Chakwera. Baba rẹ da ọpọlọpọ sọọsi silẹ.

O sọ fun akọroyin kan, Joab Chakhaza lasiko ifọrọwanilẹnu kan lọdun 2017 pé lootọ lo ni afojusun lati di dokita, nitori o gbagbọ pe oun ko nilo lati ba ipejọpọ ọpọ eniyan sọrọ nípa jíjẹ oṣiṣẹ eto ilera, nitori o jẹ ẹni to maa n tijú.

Isakoso gẹgẹ bii oloselu tabi ẹni ẹ̀mí

O sọ pe "oun ba Ọlọrun pade nigba to jẹ akẹ́kọ̀ọ́, mo si bẹrẹ si ni dari igbeaye si ilana iṣẹ Oluwa."

Okun ati imisi naa si lo fẹ ẹ lo fi dari orilẹ-ede bayii.

Mr Kampondeni tun sọ pe aarẹ mọ pe iyatọ nla lo wa laarin jijẹ olori ẹ̀sìn àti oloṣelu.

Sugbọn, o sọ pe ilana ti aarẹ yoo gbe e gba yoo yatọ, ko si ni ṣe e ni ilana bo ba o pa, bo o ba ko bu u lẹsẹ.

Yoo si lo ọgbọn inu rẹ lati da isọkan pada si orilẹ-ede Malawi.

Ọgbẹni Chakwera sọ fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa lasiko to ba wọn sọrọ pe "ko si ifoya fun awọn ti ko dibo fun".

Bi aarẹ tuntun naa ṣe fi ẹyin aarẹ to wa nipo, Peter Mutharika janlẹ, jẹ iyalẹnu. Ìdá mọkandinlaadọta ìbò lo ni.

Ọgbẹni Chakwera

Oríṣun àwòrán, AFP

Bibori ẹlẹyamẹya

Akọroyin kan, Chakhaza, sọ fun BBC pe, isẹ nla lo wa nilẹ fun aarẹ tuntun lati ma a fi ẹ̀yà yan ẹnikẹni si ipo, gẹgẹ bi ijọba to kuro nipo to fi ẹlẹyamẹya ṣe e lai fi bò.

Ojú wa lara rẹ pe ko ṣe daada ju isejọba àná lọ, awọn kan si ti n wo o boya yoo le se bẹ ẹ.

Awọn alatilẹhin aarẹ gbagbọ pe o le ṣe e, ati pe yoo ṣe amulo ilana isejọba tuntun to ni ìtọ́ni Ọlọrun ninu, to si wa ni ibamu pẹlu aini awọn ọmọ orilẹ-ede Malawi.

Ko si àní-àní, awọn igbesẹ to lagbara gbọdọ jẹ gbigbe, paapa nipa itankalẹ aarun coronavirus, ati ọna lati gbogun ti iwa ibajẹ, ati mimu idagbasoke ba ọrọ aje.

Awọn nkan wọn yii lo si ṣe e ṣe ko sọ bi isejọba rẹ yoo ṣe jẹ itẹwọgba.