Yoruba-Hausa clash: Ọlọ́pàá mú èèyàn márùn ún lórí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin Hausa àti Yorùbá l'Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu eeyan marun un lori wahala nla to bẹ silẹ laarin awọn Hausa ati Yoruba lọja Ile-epo lọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana sọ pe awọn gba lati agọ ọlọpaa Oke Odo, ede-ai-yede bẹ silẹ nigba ti Hausa kan to n ṣa ilẹ idọti ṣeeṣi ti ọkunrin Yoruba kan to rẹru lori to si ṣubu bẹẹ.
Bayii lawọn mejeeji ṣe fija pẹta, bẹẹ lawọn ẹya wọn da si ija naa lo ba di nla ti awọn ọmọ ita kan ṣi da si ija naa.
Awọn janduku kan lo lanfani yii lati ja ole, koda wọn tun di opopona mọrosẹ ilu Eko si Abeokuta pa.

Oríṣun àwòrán, others
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni ọja Oke odo ni ija naa ti waye, bẹẹni ọpọ dukia lo parẹ sinu iṣẹlẹ naa ti ọpọ eeyan si fara pa pẹlu.

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ ọlọpaa ni rogbodiyan naa ko ba di ti ẹlẹyamẹya tawọn ko ba tete kọwọ ọmọ bọ aṣọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana to ba ikọ BBC news sọrọ ṣalaye pe wọn ti da ikọ ọlọpaa kogberegbe kan si agbegbe naa to pana wahala ọhun.

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mu lẹ pe ko sẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa, bakan naa awọn mẹrin ti wọn ṣeṣe ti n gba itọju nile iwosan.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo gbe awọn afurasi marun un tọwọ ọlọpaa tẹ lọ si ileẹjọ.
- Mo dáríjì àwọn IPOB tó nà mí ní Germany nítorí wọn o m'ohun tí wọ́n ń ṣe- Ekweremadu
- Ọlọ́pàá Ogun gb'ọmọ Ìmáàmù lọ́wọ́ ajínigbé, ṣùgbọ́n wọ́n gbé ọkọ̀ ojú omi ọlọ́pàá lọ
- Wilfred Ndidi, ọmọ Nàìjíríà pa iná ògo Chelsea ní Stamford bridge
- Ọlọ́pàá Ogun gb'ọmọ Ìmáàmù lọ́wọ́ ajínigbé, ṣùgbọ́n wọ́n gbé ọkọ̀ ojú omi ọlọ́pàá lọ













