State of Osun: Iléẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní orúkọ tí ìpínlẹ̀ náà ń jẹ́ báyìí ṣe àjàjì sí ìwé òfin Nàìjíríà
Adájọ ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpińlẹ̀ Osun tí dájọ́ pé, pípe ìpínlẹ̀ Osun ní State of Osun kò bá ofin mú.
Ìdájọ́ náà wáyé lẹ́yìn ti ajàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò Kanmi Ajibola gbé ìjọba ìpińlẹ̀ Osun lọ silé ẹjọ́ nítori owó ori mílíọ̀nù meje lé díẹ̀ ti wọ́n fún pé kó san, tó sì ni owó náà kò bójú mu tó fún irú iṣẹ́ tí òun ṣe gẹ́gẹ́ bi ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn
Agbẹjọ́rò ọ̀hún kanmi Ajibola lásìkò to n bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, ọgbẹ́ni Raufu Aregbẹsọla ní òun gbé lọ sílé ẹjọ́ láti ǹkan bii ọdun mẹ́tà sẹyin nítori àwọn àyipada tó ṣe ni ìpínlẹ̀ Osun ti kò sì bá òfin mu àti pé nítoripé àkọle tó wà lórí àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi bèrè owó orí náà (Government of the State of Osun)ti ko bá òfin Naijiria mu.

Oríṣun àwòrán, others
Ajibola ni owó orí náà ko bojú mú tó bótilẹ̀ jẹ́ pe ilé ìgbìmọ̀ asofin ló gbé ofin náà kalẹ̀, adájọ gba eyí ó sì pàṣẹ pé ofin náà kò tọ̀nà bí Ajibola ṣe sọ.
Ajàfẹ́tọ ọmọnìyàn náà ní pé inú òun dùn gidigidi lóri ìdájọ ilé ẹjọ́, èyí yóò sì tún ràn àwọn ará ilú míràn lọ́wọ́ lóri lati le jà fún ẹ̀tọ́ wọ́n ti ìjọba bá ṣe oun ti kò tọ́.
Ẹ̀wẹ̀ adájọ ní orúkọ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ń pe ìpińlẹ̀ náà kò bá òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mu.
BBC News Yoruba pé kọmísọnà fún ìbánisọ̀rọ̀ nípinlẹ̀ Osun Funke Egbemode láti sọ èrò ọkàn ìjọba lóri ìdájọ ilé ẹjọ́ náà sùgbọ́n o ní ìjọba kò ni ǹkankan láti sọ lórí ìdájọ́ ọ̀hún báyìí.
" A kò tíi'ni ìdáhùn kankan sí ọ̀rọ̀ yìí báyìí, tí a ba ti ní ǹkan sọ, à ó pè yín."