Ọwọ́ tẹ Sani fọganaisa tó fipá pọ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ọdún 15 pa ní Gombe

Aworan obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọwọ ti tẹ Sani Sale, fọganaisa, ọmọ ọdun mejidinlogoji kan ni ipinlẹ Yobe to sa nle lẹyin to fipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun marundinlogun kan lo pọtọmọbinrin naa si ku si yara rẹ.

Ilu Gadaka ni ijọba ibilẹ Fika ni ipinlẹ Yobe ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, ni ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2021 ni ọmọdebinrin naa kiri akara lọ sigboro ṣugbọn ti awọn obi rẹ ko si ri i ko pada wale mọ titi ti ilẹ ọjọ naa fi ṣu.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà

Nigba ti ilẹ ọjọ keji mọ ni wọn ri oku rẹ ninu yara Sani Sale.

Ni kete ti aje ọrọ naa ṣi mọọ lori lo ti na papa bora lọ si ipinlẹ Gombe nibi ti ọwọ ọlọpaa ti pada wa tẹ ẹ.

ccc

Oríṣun àwòrán, vvv

Àkọlé fídíò, Shasha Crisis in Ibadan: Gbọ́ ohun tó ṣokùnfà ìjà láàrin Aláboyún, soo bàtà àti Hausa alá