APC vs PDP: Òótọ́ ni pé Gbanga Daniel ti kúrò ní PDP, ṣùgbọ́n kii ṣe tuntun - Agbẹnusọ PDP

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR
Alukoro ẹgbẹ oṣẹlu PDP ni Naijiria, Kola Ologbondiyan ti sọ pe o ti to ọdun diẹ ṣeyin ti gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Gbenga Daniel ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Ologbondiyan lo ṣalaye ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe Gbenga Daniel ṣẹṣẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn alukoro ẹgbẹ na sọ pe ko ṣẹṣẹ gbe igbesẹ naa nitori ni kete ti idibo Aarẹ pari lọdun 2019 lo fi ẹgbẹ naa silẹ.
- Buhari kéde ìlú kò fararọ lásìkò yìí- Ilé Igbimọ̀ Aṣofin Nàìjíríà
- A fẹ́ kí ìjọba fòfin de àwọn darandaran tó máa ń fi ìbọn Ak47 da málúù láàrín ìlú- MURIC
- Ẹ fura o! Nàìjíríà ń pín lọ díẹ̀ díẹ̀ rèé- Abdulsalami
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano ṣèrànwọ́ ₦18.5m fún àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó faragbá nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye "aarin ọsẹ ti a pari eto idibo tan lọdun 2019 ni Ọtunba Gbenga Daniel kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si sọ pe oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu kankan mọ."
"Ṣugbọn ni nnkan bi ọdun kan ṣeyin lo sọ ni gbangba pe awọn alatilẹyin oun ke si oun pe ki oun ko wọn lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC."

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR
Ologbondiyan ṣalaye pe gomina tẹlẹ ọhun sọ pe oun gba lati ṣe ohun ti awọn alatilẹyin oun n fẹ, nitori naa kii ṣe pe ó kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC.
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
Alukoro ẹgbẹ PDP naa sọ siwaju si pe loju awọn, Gbenga Daniel ko fi ẹgbẹ PDP silẹ lọ si APC, "ṣugbọn o fi ẹka ẹgbẹ APC kan silẹ lọ sinu ẹka ẹgbẹ APC miran ni."
Ologbondiyan sọ pe ẹgbẹ APC ti pin si ọna mẹrin, nitorin naa, awọn ọmọ APC ni ọrọ naa ye.
O pari ọrọ rẹ pe amọran awọn alatilẹyin Gbenga Daniel ni o tẹle.
Ni ti pe boya iyapa tabi rukerudo wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Ologbondiyan sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
- Agbaṣẹ́ṣe jẹ búlálà méjìlá lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
- Ọwọ́ tẹ Sani fọganaisa tó fipá pọ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ọdún 15 pa



















