Dangote dín owó epo bẹntiró kù sí ₦1,075

Aworan Dangote ati ibudo ifọpo kan lẹyin rẹ.

Oríṣun àwòrán, other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti din owo epo bẹntiro rẹ ku si ₦1,075 fun jala epo kan lati ₦1,175 to n ta a tẹlẹ pẹlu adinku ₦100.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa Anthony Chiejina sọ fun awọn akọroyin pe epo ti wọn ba n pin lati ori omi ni wọn yoo ta ni ₦1,050.

Ileeṣẹ naa sọ siwaju si pe ₦1,430 lawọn yoo bẹrẹ si n ta epo disu bayii, eyii to jẹ adinku ₦190 si ₦1,620 ti wọn n ta a tẹlẹ.

Wọn ni "pẹlu agbeyẹwo iye owo ti a n ta epo ti a sẹ, a ti din PMS ku lati ₦1,175 si ₦1,075 (adinkun ₦100) fun lita kan.

"A tun ti din iye owo epo disu ku lati ₦1,620 si ₦1,430 (adinku ₦190) fun lita kan."

Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbeṣe naa lo waye latari bi owo epo ṣe n lọ soke-sodo lagbaye.

Dangote sọ pe o ṣe pataki fun awọn gẹgẹ bii ileeṣẹ ti ko ṣe ojukokoro lati din iye owo epo naa ku gẹgẹ bii adinku ṣe n de ba lagbaye.

O sọ siwaju si pe nnkan bii $3 si $6 ni owo epo awọn fi le, bẹẹ ni ijọba ko si san owo iranwọ kankan fun awọn lori owo ti wọn fi n ra epo tabi owo ilẹ okeere lagbaye.

Igba akọkọ ree ti Dangote yoo din owo epo bentiro ku ni Naijiria lẹyin to ṣafinkun iye owo epo naa nigba mẹta ọtọtọ laarin ọsẹ diẹ sẹyin.

Kilode ti bẹntiro gbowo lori ni Naijiria?

Lọjọ Aje ni ileeṣẹ naa gbe owo epo si ₦1,175 fun lita kan lati ₦995 to wa tẹlẹ lọjọ keje oṣu Kẹta, ati ₦874 fun lita kan lọjọ keji, oṣu Kẹta.

Lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, adari ileeṣẹ naa, David Bird, sọ pe ohun to n ṣẹlẹ lagbaye nipa owo epo naa kan ileeṣẹ ifọpo Dangote gbọngbọn ni Naijiria.

Owo agba epo to ja walẹ si $90 lagbaye lo mu ki owo epo Dangote naa tun ja walẹ bayii.

Eyii si ni igba akọkọ ti owo epo yoo ja walẹ lagbaye lẹyin ti ogun Amẹrika ati Israel si Iran bẹrẹ.

Ogun to n waye ni Iran ọhun lo fa ọwọngogo owo epo lagbaye, ọwọngogo yii lo si jẹ ki owo epo lọ soke ni Naijiria.