Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́rin tó wà nínú àwọn bilọníà nílẹ̀ Africa

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́rin ni wọ́n wà lára àwọn èèyàn mẹ́tàlélógún tí wọ́n ní owó jùlọ ní ilẹ̀ Africa gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Forbes magazine ṣe gbé jáde fún ti ọdún 2026.
Nínú àbọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde fún ti ọdún 2026 sọ pé àwọn olówò tí owó wọn ti wọ bilọníà ní ilẹ̀ Africa ti lékún pẹ̀lú ìdá mẹ́tàlélógún tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ sí ti ọdún 2025.
Orílẹ̀ èdè South Africa ló ní àwọn olówó tó pọ̀ jùlọ pẹ̀lú àwọn bilọníà méje, nígbà tí Egypt tẹ̀le pẹ̀lú bilọníà márùn-ún, tí Nàìjíríà sì tẹ̀le pẹ̀lú bilọníà mẹ́rin.
Ìwé náà ní àwọn ìdókoòwò ẹkùn Africa ti lékún dáadáa pàápàá pẹ̀lú ìdàgbàsókè àwọn ọjà àti ṣíṣe àwárí àwọn owó kan láwọn orílẹ̀ èdè kan ní Africa èyí tó dowó fáwọn orílẹ̀ èdè náà.
Èyí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́rin tó wà nínú àwọn bilọníà náà:
Aliko Dangote $28.5bn

Oríṣun àwòrán, AFP
Alága iléeṣẹ́ Dangote Group of Companies, Aliko Dangote ṣì wà nípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó lówó jùlọ ní Africa.
Àtẹ̀jáde Forbes magazine sọ pé Dangote ní owó $28.5bn.
Wọ́n ní láàárín ọdún 2025 sí 2026, owó Dangote- ẹni tó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Kano lékún pẹ̀lú bílíọ̀nù mẹ́rin lé ọwọ́ mẹ́fà dọ́là ($4.6bn).
Forbes ní ohun tó mú ọlà Dangote lékún láàárín ọdún kan ni iléeṣẹ́ sìmẹ́ǹtì rẹ̀ tí ìgbéga ńlá bá láàárín ọdún kan.
Wọ́n ní èrè ìlọ́po méjì ni iléeṣẹ́ Dangote Cement Company ní ọdún 2025, èyí tó mú kí èrè rẹ̀ wọ tíríọ̀nù kan náírà.
Dangote tún ti tọwọ́bọ àdéhùn kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ China kan èyí tí owó rẹ̀ jẹ́ irinwo mílíọ̀nù dọ́là ($400m) láti mú ìgbòòrò bá ilé ìfọpo rẹ̀ nígbà tó bá fi máa di ọdún 2029.
Abdulsamad Isyaka Rabiu $11.2bn

Oríṣun àwòrán, BUA group
Ọmọ Nàìjíríà míì tó wà lára àwọn olówó bilọníà nílẹ̀ Africa tún ni alága BUA Group, Abdulsamad Isyaka Rabiu.
Gẹ́gẹ́ bí Forbes magazine ṣe sọ, owó tó bilọníà náà ti lékún pẹ̀lú ìdá ọgọ́fà.
Abdulsamad Rabiu tí òun náà wá láti ìpínlẹ̀ Kano ni owó rẹ̀ ti wọ $11.2bn báyìí láti $6.2bn tó wà ní ọdún tó kọjá.
Òun ló wà nípò kẹta àwọn tó lówó jùlọ ní Africa báyìí láti ipò kẹfà tó wà lọ́dún tó kọjá.
Forbes magazine sọ pé iléeṣẹ́ BUA Cement Company wà lára àwọn iléeṣẹ́ tó lówó jùlọ ní Africa tó sì ṣokùnfà bí Rabiu ṣe gòkè láàárín ọdún kan.
Mike Adenuga – $6.5bn

Oríṣun àwòrán, others
Alága iléeṣẹ́ Globacom, Mike Adenuga ni ọmọ Nàìjíríà kẹta tí orúkọ rẹ̀ wà lára àwọn ọmọ Nàìjíríàt ó lówó jùlọ ní Africa.
Forbes magazine ní Mike Adenuga ló wà ní ipò kẹfà àwọn èèyàn tó lówó ní Africa tí àpapọ̀ iye owó rẹ̀ sì tó $6.5bn.
Adenuga tún ni alága iléeṣẹ́ Conoil, iléeṣẹ́ epo rọ̀bì tó ti pẹ̀ka dé ìbánisọ̀rọ̀, ilé ìfowópamọ́, epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì.
Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ogun lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ni Mike Adenuga.
Femi Otedola – $1.3bn

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ Nàìjíríà kẹrin tí orúkọ rẹ̀ tún wọ ìwé àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa tó lówó jùlọ ni Femi Otedola.
Bilọníà náà tó jẹ́ alága iléeṣẹ́ Geregu Power Plc, iléeṣẹ́ ohun àmúṣagbára, ló wà ní ipò kejìlélógún nínú àwọn mẹ́tàlélógún.
Gẹ́gẹ́ bí magazine náà ṣe sọ, Otedola pàdánù owó tó $200m látàrí bó ṣe tà lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ rẹ̀ tí àpapọ̀ owó rẹ̀ sì jẹ́ $1.3bn báyìí.
Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Eko lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ni Femi Otedola.



























