Torí pé àwọn èèyàn ò rí ààrín èmi àti Allwell Ademola ni wọ́n fi ń sọ pé a ń fẹ́ra, àmọ́ Ọlọ́run yan án sínú ayé mi láti tọ́ mi sọ́nà – Rotimi Salami oṣere

Àkọlé fídíò, Ọlọ́run yan Allwell Ademola sínú ayé mi ni láti tọ́ mi sọ́nà – Rotimi Salami oṣere
Torí pé àwọn èèyàn ò rí ààrín èmi àti Allwell Ademola ni wọ́n fi ń sọ pé a ń fẹ́ra, àmọ́ Ọlọ́run yan án sínú ayé mi láti tọ́ mi sọ́nà – Rotimi Salami oṣere

Gbajumọ oṣere tiata, Rotimi Salami ti sọrọ lori iku korikosun rẹ, Allwell Ademọla to di oloogbe loṣu diẹ sẹyin.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Rotimi Salami ṣalaye wi pe oun ri oloogbe Allwell Ademọla gẹgẹbi ẹni ti Eleduwa ran sinu aye oun lati le maa tọ oun sọna ni.

O ni gbogbo awọn to ba n sọrọ pe boya ajọṣepọ ifẹ ikọkọ n bẹ laarin awọn mejeeji le maa wi ohun to ba wu wọn nitori pe ggẹbi ẹgbọn loun mu oloogbe naa.

'Bí àyẹ̀wò DNA bá sọ pé èmi ni mo lọmọ, bí ọmọ náà bá ti dá mi mọ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá ẹ̀, èmi ò jẹ́ fi irú ọmọ bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ o'

Bakan naa lo tun sọrọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn obinrin lori ayelujara eleyi to ni ko si ipalara nibẹ fun oun tabi ẹbi oun nitori pe iyawo oun naa mọ bo ṣe nlọ ati pe nnkan ẹyọ kan ti iyawo oun ko fẹ naa ni abuku, eleyi ti oun pẹlu si n rii daju pe oun ko tabuku rẹ tabi fi ọrọ rẹ tayin niwaju ẹnikẹni yala ko jẹ ọkunrin.