Ẹbí Allwell Ademola sọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀ àti ìgbà tí ètò ìsìnkú lè wáyé

Oloogbe Allwell Ademola wọ aṣọ funfun balau

Oríṣun àwòrán, Rotimi Salami/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹbi gbajumọ oṣere to jáde láyé, Allwell Ademola, ti sọrọ fun igba akọkọ lori iku gbajugbaja olootu ati adari ere naa.

Ninu atejade kan ti ẹbi náà fi sita, idile Ademola dupẹ lọwọ awọn ọrẹ, awọn akẹgbẹ oloogbe ati gbogbo eeyan fún ibanikẹdun wọn.

Ẹbi Ademola sọ ninu atẹjade ti Ọgbẹni Adegboyega Adebayo buwọ́lu pe àwọn ti gba fun Ọlọrun lori iku Allwell, bo tilẹ jẹ pe ọkan awọn gbọgbẹ.

Ẹbi Ademola sapejuwe Allwell gẹgẹ bí "ọmọbinrin idile Ademola lati ipinlẹ Ogun to ṣe e mu yangan.

Ọmọ ọmọ ọmọ Ọba Alake Ilẹ Egba ni Allwell i ṣe, o si jẹ ẹni to jara mọ iṣẹ rẹ.

Lati igba ewe rẹ titi ti o fi dagbere faye ni Allwell jẹwọ ara rẹ gẹgẹ bii oṣere, adari ere, olootu ere ati akọrin ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyìn.

Allwell ni ipa ribiribi ninu ayé ọpọ eeyan lagbo ere tiata, nipa lilo ẹbun ti Eledua fi jinki rẹ."

Ẹbi Ademola tun sọ ninu atẹjade ti won fi sita pe awọn mọ riri adura ti ọpọ eeyan n gba fún ẹbi Allwell lasiko yii.

"Awa ẹbi Ademola dupẹ gidi fún ìfẹ, atẹjiṣẹ ibanikẹdun ati ìdàrò ẹyin eeyan lori iku ọmọ wa.

Atilẹyin yin n mu wa lọkan le lasiko yii lori iku Allwell.

A gbadura pe kí Eledumare tẹ ẹ si afẹfẹ rere, kí o si tu awa ẹbi rẹ ninu."

Ẹbi Ademola ni awọn yoo maa kede bi eto isinku Allwell yoo ṣe lọ laipẹ.

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni Allwell Ademola dagbere faye niluu Eko.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Àwọn òṣèré tíátà ń ṣèdárò Allwell Ademola tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 49

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati ọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kejila yii ti gbgbajumọ oṣere, Allwell Ademola, ti jade laye lawọn akẹgbẹ rẹ ti n ṣe idaro rẹ.

Iroyin iku Allwell mi ori ayelujara titi tori ojiji lo ba ọpọ eeyan to gbọ iroyin naa.

Ohun to ya ọpọ lẹnu ni pe gbajumọ oṣere naa si ṣe fidio kan ninu eyi to ti kọrin wi pe oun yoo la ọdun yi ja ni bii ọjọ kan si asiko iku rẹ.

Orin Baba Ara pẹlu akọle ''Bi a ba n joyin, bi a ba n jadun; Ka ma gbagbe pe ajeji la jẹ laye'' ni Odunlade Adelade fi bẹrẹ idaro tiẹ loju opo Instagram rẹ.

Odunlade pariwo ori oun, o si lo aworan to n ṣapujuwe pe inu oun bajẹ, ọkan oun si gọgbẹ gidi gan an loju opo rẹ.

Adekola wa gbadura pe ki Eledua tẹ Allwell si afẹfẹ rere.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Ademola Amusan, ti ọpọ mọ si Mr Latin sọ pe ọkan oun wuwo nigba toun gbọ nipa iku Allwell.

Mr Latin ni ''a ti padanu Allwell Ademola, akọṣẹmọṣẹ olootu ere, adari ere ati akọrin.

Allwell ti fi ipa ti ko le parẹ lelẹ ninu aye gbogbo eeyan to mọ ọ.

Allwell, o wa saye, o ṣe ọpọ nnkan, o si jẹ iwuri fun ọpọ eeyan.

A o le gbagbe rẹ lailai, sun re o.''

Ibeere ni Iyabo Ojo fi bẹrẹ idaro tiẹ nigba to sọ pe ''Ọlọrun, kilode tawọn eeyan rere ṣe n ku ni rewe rewe?

Iyabo ni kayeefi ni iku Allwell jẹ fun oun, amọ, o sọ pe ko ṣeni to le ba Ọlọrun ro ẹjọ.

Gbajumọ oṣere naa wa gbadura wi pe ki Allwell maa sinmi laya Olugbala rẹ.

Muyiwa Ademola ni tiẹ sọ pe iroyin iku Allwell jẹ ọkan lara iroyin to ba oun ninu jẹ julọ.

Agba oṣere naa ni ''mi o tiẹ mọ nnkan ti mo le kọ.

Ṣugbọn ti mo ba ṣẹ ọ lọna kọna, forijin mi.

Ẹ jẹ ka maa ranti pe, ọjọ kan n bọ bayii ti gbogbo wa naa yoo ku.

Ọkan mi gbọgbẹ, mo si fẹ ko fuyẹ.

Emi naa ti darijin ẹnikẹni to ba ṣẹ mi lọkan mi.

Ẹ jẹ ka maa lepa alaafia tori kosi nnkan kan ninu aye yii.

Sun re o Allwell Ademola.

Iroyin ni ile iwosan Ancilla, to wa lagbegbe Agege, niluu Eko ni oṣerebinrin ọhun dakẹ si.