Àwọn ajínigbé kọlu ìlú Adanla ní Kwara, jí èèyàn mẹ́sàn-án gbé lọ, yìnbọn pa ẹnìkan

Oríṣun àwòrán, Kwara police
Awọn ajinigbe tun ti sọsẹ ni ipinlẹ Kwara lẹyìn tí wọn sekọlu si ilu Adanla to wa ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ naa.
Iṣẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ keji ọdun keresimesi ni nnkan bi ago meje alẹ ti ko ipaya ba awọn eeyan ilu naa bayii.
Ọgbẹni Yusuf to jẹ oṣiṣẹ atunase ni ilu Adanla fidi rẹ múlẹ pe eeyan mẹsan-an ni wọn ji gbe ni ilu naa.
O fikun ọrọ rẹ pe ọmọ ile kan naa lawọn ti wọn ji gbe lọ naa.
Yusuf salaye pe awọn to wa sọdun keresimesi ni ilu Adanla lawọn eeyan ọhun.
Araalu Adanla náà tún sọ pe mọlẹbi oun wa lara awọn ti wọn ji gbe naa.
Ohun tí a gbọ́ ni pe awọn ọlọpaa ati awọn eleto aabo miran ti de si ilu naa bayii.
Ọgbẹni Yusuf salaye pe se ni ọrọ di bo o lọ ya n mi lasiko ti awon ajinigbe ọhun ya wọ inu ilu naa .
O ni awọn eeyan n se faaji ọdun lọwọ ni lasiko ti ikọlu naa waye.
Yusuf sọ pe inu idaamu ni oun at'awọn araalu naa wa bayii lẹyìn iṣẹlẹ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Ajayi ti oun naa jẹ ọmọbibi ilu Adanla, sọ pe inu igbo ni oun salọ lalẹ ọjọ naa lasiko ti awọn agbebọn náà sadeede da ibọn bo ilẹ.
Ajayi salaye pe ẹni ti ibọn ba, wọn ti gbe e lọ ile iwosan fún itọju, amọ, o tun fidi rẹ múlẹ pe awon ajinigbe ọhun yinbọn pa ẹnikan.
BBC Yorùbá kan si alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Arabinrin Ejirẹ Toun Adéyemí, lori iṣẹlẹ naa; ṣugbọn ko tii fesi titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ.















