Ìjọba Naijiria kéde àwọn ajínigbé àtàwọn jàndùkú agbébọn bíi agbésùnmọ̀mí

Aworan agbebọn ọkunrin ninu igbo, o de fila dudu, wọṣọ alawo aro

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lodi si bi wọn ṣe n ka ijinigbe si ikọlu tabi ẹsun lasan tẹlẹ, ijọba apapọ Naijiria ti kede pe oun ti ka ijinigbe si ẹsun igbesunmọmi bii ti awọn akọluni yoku ti wọn n gbebọn da orilẹede yii laamu.

Ọjọ Aje ana ni Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris, kede eyi nibi ipade awọn oniroyin ti wọn fi kasẹ ọdun 2025 nilẹ, niluu Abuja .

Bakan naa ni ijọba apapọ kede pe ẹgbẹ yoowu to ba n dihamọra ogun, to n kọlu awọn eeyan ti di agbesunmọmi (Terrorists).

Igbesẹ yii ti yatọ si bi wọn ṣe n fi oju ikọlu lasan wo jiji ọpọ eeyan gbe tẹlẹ, ati bi wọn ṣe n wọnu ilu ti wọn n da awọn eeyan si hilahilo.

"Lati isinyi lọ, ẹgbẹ yowu tabi eeyan to ba dihamọra ogun, ti wọn n ji awọn ọmọ wa gbe, ti wọn n kọlu awọn agbẹ wa, ti wọn si n daamu awọn ilu wa ni a o maa fi iya to tọ jẹ, ti a o si maa ka wọn si agbesunmọmi.

"Ni bayii, asiko iruju ti kọja. Bi o ba ko ipaya ba awọn eeyan wa, boya ẹgbẹ kan lẹ jẹ tabi ẹnikan ṣoṣo, agbesunmọmi ni o, bẹẹ la o si maa pe ọ. Ko si orukọ kankan ta o pe e ju bẹẹ lọ mọ."

Bẹẹ ni Minisita eto iroyin wi.

O fi kun un pe igbesẹ yii yoo tun jẹ kijọba ro awọn ẹṣọ alaabo lagbara si I, yoo si ran ipinnu ṣiṣe kia lọwọ.

Bakan naa lo ni ijọba yoo pese awọn akọṣẹmọṣẹ ẹṣọ alaabo ati irinṣẹ to yẹ, awọn ọdẹ aṣọgbo yoo si wa.

O ni awọn eeyan naa yoo maa ṣọ agbegbe, wọn yoo mọ nipa agbegbe kọọkan gẹgẹ bii ọmọ ibilẹ ibẹ, wọn yoo si le tete mọ ibi tawọn ẹni ibi fi n ṣe ibuba ninu igbo.

Awọn ọdẹ aṣọgbo yii naa ni minisita sọ pe lara ojuṣe won ni lati dena ibi ti awọn ọdaran n gba kọja ti wọn ti n pin nnkan oogun.

Ojuṣe wọ si tun ni lati tu agọ awọn ọdaran palẹ, ki wọn si le fi awọn agbẹ lọkan balẹ lawọn ibi ti wọn ko ti ri oko lọ mọ nitori ikọlu awọn agbesunmọmi.