Àwọn tó gba wèrè mẹ́sìn ló kórìíra àṣà àti ìṣeYorùbá, àṣà wa ò gbọdọ̀ parun - Àwọn olóyè ìlú Osi kìlọ̀

Egungun to wa ninu ẹku mu igi kan lọwọ pẹlu ero lẹyin rẹ, ati mama agba to ru igba lori pẹlu ilẹkẹ lọrun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn oloye ilu Osi nipinlẹ Kwara ti rọ gbogbo ìran Yoruba lati ma ṣe jẹ ki asa ilẹ Yoruba parun nitori ẹṣin.

Awọn oloye naa sọ eyi di mimọ nibi ayẹyẹ ọdun ilu Osi to waye lanaa, ọjọ Abamẹta ni ilu naa to wa ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Asiwaju ilu ọhun, Ajagunfẹyinti Samuel Afolayan sọ pe ẹsin ati aṣa ko papọ rara tori pe ọtọ lasa, ọtọ si ni ẹsin naa.

Oloye naa ṣalaye pe awọn ohun to jẹ asa ati ise Yoruba ni awọn eniyan ti n pa ti, nitori ẹṣin Kristẹni ati ẹṣin Islam ti wọn n ṣe.

O ni ko yẹ ko ri bẹẹ nitori ọtọ laye awọn mejeeji, ko si yẹ ki ọkan di ekeji lọwọ.

Ọgbẹni Afolayan sọ pe "lode oni, ọpọ ri asa ati ise ilẹ Yoruba gẹgẹ bii ibọrisa, eleyi si n fa ifasẹyin fun asa ati ise wa.

"Ara asa wa ni bi awọn ọdọbinrin ṣe maa n wọ aṣọ ibilẹ, ti wọn yoo si jade lati jo nibi ayẹyẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe lonii.

"Pataki rẹ ni wi pe ibi ti wọn ti n se ere yii ni wọn ti maa n ri ọdọkunrin lati fẹ ni ọkọ.

"Ko si aye lati pade ọdọkunrin nibi ti awọn obinrin ti n ran iya wọn lọwọ ni ile, bẹẹ si ni ọdọkunrin naa ko le ri obìnrin fẹ nibi to ti n tẹle baba rẹ lọ soko.

"Amọ nibi ayẹyẹ bayii ni awọn igun mejeeji yoo ti ni ajọsepọ, wọn yoo si lee fẹ ara wọn.

"O tumọ si pe ijo ati ilu ti wọn n lu, kii se iborisa rara, asa ati ise ilẹ Yoruba ni.''

Ajagunfẹyinti Afolayan ni gbogbo eeyan lo mọ ohun ti ẹṣin fẹ ki wọn se, gẹgẹ bii Kristẹni tabi Musulumi.

O ni awọn eeyan mọ ohun ti Ọlọrun fẹ ki wọn se, ati pe awọn asa ilẹ Yoruba ko odi si ilana Olorun.

Ọgbẹni Afolayan sọ pe ẹni to ba mọ ijinlẹ ninu ẹsin to n se, o ma ri iyatọ ninu asa ati ẹṣin, nitori o ni nnkan to fidi ẹṣin mulẹ.

Ajagunfẹyinti naa ni ''asa jẹ ounjẹ ti a n jẹ, aṣọ ti a n wọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.''

''Were lọpọ eeyan gba mọ ẹṣin lo jẹ ki wọn korira asa ati ise ilẹ Yoruba''

Awọn egungun n jo nibi ayajọ ọjọ ilu Osi nipinlẹ Kwara

Nnu ọrọi tirẹ, Obanla ti ilu Osi, Oloye James Afolayan, sọ pe were ni awọn eeyan gba mọ ẹṣin lasiko yii to jẹ ki wọn korira asa ati ise ilẹ Yoruba.

Obanla sọ pe ko si ibi ti ko si asa lagbaaye, o ni asa ṣe pataki pupọ to bẹẹ ti ko yẹ ko parun.

O salaye pe yatọ si gbigbe asa ati ise larugẹ, ayẹyẹ naa wa fun ikowojọ fun idagbasoke ilu.

Bakan naa, Họnọrebu Abolarin Ganiyu Gabriel to n soju ẹkun Ekiti ni ile igbimo asofin Kwara sọ ọ di mimọ pe ijoba n ko ipa ribi ribi lati mase jẹ ki asa ati ise ẹkun naa parẹ.

Saaju ni awọn ọdọ lọkunrin ati lobinrin ti fi ijo ati ilu da awọn ori ade ati tonile talejo to pesẹ sibi ayẹyẹ naa lara ya.

Orisiirisii eegun lo si tun jade lati sere fun awọn eniyan.

Koda, wọn gbe awọn akara nla kan ti wọn din bi isu jo yika oju agbo lati fi da awọn eniyan lara ya.

Akara yii ni wọn pe ni akara dugba, ko si si ilu miran ti a ti le ri eru rẹ yatọ si ilu Osi, gẹgẹ bi nnkan tawọn araalu ilu naa sọ.