Àwa gómìnà méjì ló kù nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ṣùgbọ́n ẹ̀rù kò bà wá - Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, x/Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti jẹ ko di mimọ pe mimi kankan o mi ẹgbẹ oṣelu PDP bi o ti lẹjẹpẹ awọn gomina meji pere lo ku ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Lọjọ Aje yii ni, Gomina Dauda Lawal ti ipinlẹ Zamfara kọwe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si ku Gomina Bala Muhammed ti ipinlẹ Bauchi ati Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo gẹgẹ bii gomina to ku ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ ninu Abuja, o ni lootọ ni ohun to n sẹlẹ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ko lọ botiyẹkolọ, to si n ṣe akoba fun eto ijọba awarawa.
Makinde ni awọn meji pere lo ku bayii gẹgẹ bii gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn ẹru ko ba awọn ara rara.
"Ti wọn ba n sọ itan asiko yii, wọn yoo ma sọ itan eto ijọba awarawa, ti awọn eeyan ati araalu yoo si gbaruku ti wa .
"Mo le sọ pe asiko yii yoo ka ẹsẹ nilẹ. Oun yoo rekọja.
"Gbogbo nnkan ti a ba n ṣe bayii, ka ranti awọn ipa ti a ko lasiko yii."
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Adolphus Wabara ni o ṣe koko lati wa ọna abayọ si iṣoro ẹgbẹ oṣelu PDP, ati pe nisiyi ti idajọ ile ẹjọ si ti farahan, asiko ti to lati ṣe atunṣe lori kudiẹkudiẹ ẹgbẹ oṣelu naa.
"Idajọ lati ṣe atunṣe ni nitori a bọwọ fun ofin. Anfani ree fun wa lati tun gbe igbesẹ miran. Idi ree ti a fi peju sibi
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Abuja da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party pè nù láti tako ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja tó ní kí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Independent National Electoral Commission, INEC láti má gba àbọ̀ àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún àti Kẹrìndínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.
Nínú ìdájọ́ tí gbogbo àwọn adájọ́ mẹ́tẹ́ẹ̀ta ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà panupọ̀ lórí ìdájọ́ lórí ẹjọ́ tí PDP pè náà.
Ilé ẹjọ́ náà ní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí PDP pè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga kọ́kọ́ gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá jẹ́ ohun tó tọ̀nà.



























