Obìnrin kan dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí ilé ẹru jálé e lórí nílu Eko

LASEMA

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Obirin kan ti dero ile iwosan lẹyin ti ile ẹru ja lee lori lagbegbe Iyana Ipaja nipinlẹ Eko.

Ko pẹ ti iṣẹlẹ naa waye ti ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, LASEMA, lọ si ojuko iṣẹlẹ ọhun lati doola ẹmi obirin naa.

Ile ẹru ọhun to ga to iwọn ẹsẹ bata ogoji lo ja le obinrin naa lori lati ori afara, ti obinrin ọhun si ha sabẹ ile ẹru naa.

LASEMA

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ọpọ awọn eeyan agbegbe ti iṣẹlẹ nmaa ti waye lo gbiyanju lati ran awọn oṣiṣẹ LASEMA lọwọ ko lee tete ri obinrin naa yọ labẹ ile ẹru ọhun.

Ọga agba ajọ LASEMA, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu sọ fun awọn oniroyin ninu atẹjade kan pe, awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti doola ẹmi obirin naa.

Lẹyin naa ni wọn gbe obinrin ọhun lo si ile iwosan fun itọju.