Ojú àti orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó yìnbọn sókè lẹ́yìn olórin kan rèé - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @Princemoye1
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni ọwọ ti tẹ awọn ọlọpaa to yinbọn si oke ni ilu Kano.
Laipẹ yii ni fidio ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nibi ti awọn ọlọpaa ti wọn n sọ gbajugbaja olorin kan nibẹ ti ṣe aṣemaṣe.
Awọn ọlọpaa mẹtẹẹta lo yinbọn si oke lati sẹ ajọyọ bi awọn eniyan to fi mọ ọmọde ati agba ṣe n ki olorin naa to fẹ wọ inu ọkọ rẹ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi fi lede lori Twitter lo ti fi oju awọn mẹtẹẹta han ninu aworan to fi sibẹ.
Bakan naa lo darukọ awọn ọlọpaa naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọwọ̀ ti tẹ ọlọ́pàá tó yìnbọn sókè lásìkò tí olórin kan n kọjá ní Kano
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ni awọn ti fi panpẹ ọba mu ọlọpaa kan to sẹ aṣemaṣe nipa yin yin ibọn si oke lasiko ti elere kan n kọrin ni ilu Kano.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, CSP Olumuyiwa Adejobi lo fi iroyin naa lede ni oju opo Twitter rẹ.
Eyi ko ṣẹyin fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan nibi ti ọlọpaa kan to n ṣọ olorin takasufe ni ilu Kano, Dauda Kahutu Rarara, ti bẹrẹ si ni yin ibọn soke nibi ti obinrin ati awọn ọmọde wa laarin ero to ṣubu ọkọ olorin naa.
Awọn to fesi si fidio naa kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati fi ọlọpaa naa jofin lati jẹ ẹkọ fun awọn toku.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ninu esi rẹ, Adejobi ni awọn ọlọpaa to ṣe aṣemaṣe naa ni awọn ti mu.
O ni wọn wa ni gbaga ọlọpaa lọwọlọwọ ni Kano nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ.
‘’A ti bẹrẹ lati fi iya to tọ jẹ awọn to ṣe aṣemaṣe yii ti wọn si tabuku ileeṣẹ ọlọpaa lati maa sa akọrin ni igboro.’’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Bakan naa ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria naa dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn fi fidio naa ṣọwọ si wọn, pe wọn ku iṣẹ.
O tun fi asiko yii kesi awọn araalu lati tubọ maa ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa fun idagbasoke orilẹede Naijiria.
‘’N2m, kírétì 5 ọtí ẹlẹ́rìndòdò, káàdì ìpè fóònù àti paálí sìgá róòlù kan la fi dóòlà ẹ̀mí aya Ọba Ògbóni lọ́wọ́ ajínigbé"

Oríṣun àwòrán, Others
Iyawo babalawo ti wọn ji gbe, Rasidat Olakisan, ti gba ituṣilẹ lọwọ awọn ajinigbe ni agbegbe Imesi-Ile, ni ipinlẹ Osun.
Ọjọ Aiku, ọṣẹ to kọja ni wọn ji Rasidat to jẹ iyawo Babalawo, Adetoyese Olakisan, ti wọn n pe ni Oba Ogboni Agbaye, gbe lọ.
Amọ Ọjọ Aje ọṣẹ to kọja naa ni ẹnikeji ti wọn jigbe sa kurọ nibi ti wọn ji gbe lọ, amọ ti Rasidat wa ni ahamọ wọn.
Ori ko Rasidat naa yọ nigba ti ikọ ọlọpaa ati ẹṣọ alaabo Kiriji Heritage Defenders yabo agbegbe Aba Panu ni ilu Ekiti, nibi ti wọn ji wọn gbe lọ.
Adari ikọ alaabo Kiriji Defender ṣalaye bi wọn ṣe doola ẹmi aya ọba Ogboni
Adari ikọ Kiriji Defender, Ademola Ekundayo ṣalaye bi wọn ṣe doola ẹmi arabinrin Rasidat ti wọn gbe lọ naa.
Ekundayo ni awọn ajinigbe naa doju ibọn kọ wọn ni inu igbo to wa laarin ipinlẹ Osun ati Ekiti.
O ni abule Aba Paanu to wa laarin Oke-Imesi ati Ikoro-Ekiti ni awọn ti doola ẹmi arabinrin naa nibi ti awọn ajinigbe naa ti n ṣọla.
‘’Bi a ṣe n debẹ, awọn ajingbe naa ti yi wa ka, ti a si na miliọnu meji naira lọ si wọn.
Ni kete ti wọn ri pe a pọ. ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn, a ri meji ninu wọn, ti wọn di obinrin naa mu, amọ wọn fi obinrin naa silẹ, ti wọn si salọ.
‘’Agbegbe oke naa ni awọn ajinigbe naa ti n ṣọṣẹ, ti wọn si beere fun katọọnu marun un ọti ẹlẹrindodo, siga roolu kan, kaadi ipe MTN, GLO ati awọn miran.’’
O ni ijọba gbọdọ naani awọn ẹṣọ alaabo abẹle, ki eto aabo Niajiria le gberu si.
Adari ikọ eto alaabo naa ni ipenija kan soso ti awọn ni pe awọn ko ni ohun ijagun amọ awọn le wọ inu igbo lati koju awọn ajinigbe yii lai fi bi wọn ṣe pọ to ṣe.
















