Adajo tẹ́lẹ̀ ní iléẹjọ́ ní àgbáyé, Bola Àjibola jáde láàyè léni ọdún 89

Oríṣun àwòrán, Others
Adajo Àgbà tẹ́lẹ̀ ni ileẹjo ni àgbáyé, Bola Ajibola jáde láàyè.
Ọjọ́ kejilelogun ọdún 1934 ni wọ́n bí olóògbé Bola Ajibola ni ìdílé ọba òwú Abẹ́òkúta.
Bola Ajibola ni oludasile ilé ẹ̀kọ́ gíga Crescent University tí ó wà ní Abẹ́òkúta.
Ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Alákóso fún eto ìdájọ́ lorile-ede Nàìjíríà àti àwọn ipò pàtàkì míràn nínú ètò ìdájọ́ kakiri àgbàlá ayé.
Bọlá Ajibola ni olórí ọmọ ọba ní ìdíle ọba Owú nígbà ayé rẹ.
Ìkéde ikú rẹ wáyé ni owuru kùtùkùtù ọjọ́ àìkú láti ẹnu àkọ́bí rẹ lọkunrin, Ségun Ajibola SAN.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa Bola Ajiboye to doloogbe
Bọlá Ajibola lọ sí ilé ìwé alakobere Baptist day school tí ó wà ní òwú àti ilé ẹ̀kọ́ gírámà Baptist Boys high school BBHS abeokuta láàárín ọdún 1942 sì ọdún 1955.
Ní ọdún 1958, Bola Ajibola kẹ́kọ̀ọ́ gboyè imọ òfin ni ile ẹ̀kọ́ Holborn College of law ni ìlú London. Wọn pé sì àjọ àwọn amofin ni Lincoln's Inn ni ọjọ́ ketadinlogbon oṣù konkonla, ọdún 1962.
Bọlá Ajibola tí fi ìgbà kan jẹ́ Ààrẹ àwọn agbejoro lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàárín ọdún 1984 sì 1985 kí ìjọba ológun lábẹ́ àṣẹ Ogagun Ibrahim Babangida wá yàn gẹ́gẹ́ bí Alakoso fún eto ìdájọ́ lorile-ede Nàìjíríà láàárín ọdún 1985 sì 1991.
Eto ìsìnkú rẹ yóò wáyé lónìí ní déédéé agogo merin ìrólé ni Islamic Mission for Africa TI ó wà ní ìsàlẹ̀ abese Abiola way n'ilu Abẹ́òkúta ni ìlànà eto ìsìnkú àwọn Mùsùlùmí.












