Ó ti ju ìgbà méjìlá lọ tí wọ́n ti kéde ikú mi– Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, @Evangelist Ebenezer Obey Instagram
Lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii ni àgbà ọ̀jẹ̀ olorin Juju to di akorin ẹmi nni, Ẹfanjẹliisi Ebenezer Remilekun Fabiyi tawọn eeyan mọ si Obey, pe ọdun mẹtalelọgọrin (83) loke eepẹ.
Nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹtalelọgọrin rẹ to waye nipinlẹ Eko ni Obey ti ṣalaye pe o ti le ni igba mejila ti wọn ti kede iku oun.
Alagba Ebenezer Obey sọ pe, " Mi o le gbagbe ọlọkan-o-jọkan ailera ti mo koju laye mi, eyi to mu mi ṣe ọpọ iṣẹ abẹ.
" Mo dupẹ f'Ọlọrun to mu mi bori awọn akoko iṣoro naa. Emi ti wọn ti kede iku mi kọja igba mejila, sibẹ, Ọlọrun da mi si"
"Idi niyi ti mo fi n ṣe aye mi lọ pẹlu ọkan ọpẹ si Ọlọrun, pẹlu gbogbo idojukọ ailera ti mo ni, mo ṣi n lọ si ọna jinjin ati itosi lati kọrin lẹni ọdun mẹtalelọgọrin. Oluwa nikan lo le ṣeyi, mo si fi gbogbo ogo fun un."
Awọn eeyan nla lawujọ lo peju-pese sibi ayẹyẹ ọjọọbi yii, lara wọn ni aarẹ tẹlẹ ni Naijiria; Oloye Olusegun Obasanjo, Alaaji Wasiu Ayinde Marshal (KI De Ultimate) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ta a ni Ebenezer Obey Fabiyi?

Oríṣun àwòrán, @Evangelist Ebenezer Obey Instagram
Ilu Idogo, nipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Oloye Remilekun Olasupo Aremu Fabiyi, lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 1942.
O kọrin Juju fun ọdun mẹrindinlaadọrin ko too gbọ ohun Oluwa to si di ajihinrere. Baba Miliki lawọn eeyan mọ Obey si ni gbogbo asiko ọdun 1950 sisalẹ.
Ọdun 1964 lo da ẹgbẹ orin rẹ to pe ni International Brothers silẹ.
Awọn orin ọlọkan-o-jọkan to kun fun arojinlẹ ati miliki ni aye mọ Ebenezer Obey mọ.
Eyi lo ṣe jẹ kayeefi fun awọn onifaaji to n fẹran rẹ nigba ti wọn gbọ pe Baba Commander bi wọn tun ṣe maa n pe e ko kọrin aye mọ.
Ni awon akoko ti Obey n kọrin onimiliki naa ni awọn kan n gbe e kiri pe o gbe lukudi mi, iyẹn oriṣi oogun owo kan to maa n mu ikun tobi.
Ebenezer Obey fi kọrin nigba naa pe '' Baabu Lukudi''.
O loun ko mu lukudi kankan, bẹẹ ni oun ko gbe oogun oloro lọ siluu oyinbo bawọn ayẹ ṣe n gbe e kiri nigba naa.
Obey padanu iyawo rẹ, Ajinhinrere Juliana Obey-Fabiyi, lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2011.
Bakan naa ni ọmọ agba ọjẹ olorin yii torukọ rẹ n jẹ Olayinka Olalekan, jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọta ni 2022.
Gẹgẹ bi Oloye Ebenezer Obey Fabiyi funra rẹ ṣe wi, oriṣiiriṣii ailera lo ti koju, ṣugbọn Ọlọrun ninu aanu rẹ da ẹmi rẹ si, lati tun ri ọjọọbi ọdun kẹtalelọgọrin.
Díẹ̀ lára orin tí Olóyè Ebenezer Obey kọ

Oríṣun àwòrán, Others
Lara awọn orin ti Baba Commander kọ nigba to wa ni Sango ode ni:
Aimasiko
Edumare Soro Mi Dayo
Iba Lo Ye Ka se
Ota Mi Dehin Lehin Mi
Oro Oluwa Ede
Board Members
Juju jubilation
Ebenezer Obey in London ati bẹẹ bẹe lọ.














