Àwọn àwòrán tó jẹ ojú ní gbèsè láti ibi ìwúyè Aláàfin Abimbola Owoade
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ọjọ Abamẹta, ọjọ karun un, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, jẹ ọjọ manigbagbe ni ilẹ Yoruba, paapaa julọ, ilu Oyo.
Eyi ko ṣẹyin bi ọba tuntun, Alaafin Abimbola Akeem Owoade I ṣe gun ori apere awọn baba nla rẹ.
Eyi waye lẹyin ti Ọba Lamidin Adeyemi III waja lọdun 2022.
Alaafin Owoade ni Alaafin Kẹrindinlaadọta to jẹ niluu Oyo.
Akojọpọ diẹ ree lara bi ayẹyẹ iwuye naa ṣe lọ, ninu aworan.
Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, naa darapọ mọ awọn eeyan nlanla to pejọ sibi iwuye Alaafin tuntun, Ọba Abimbola Akeem OwoadeÀkọlé àwòrán, Ooni Ile-Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi naa wa ni ikalẹ lati dawọ idunnu pẹlu Oba Owoade IÀkọlé àwòrán, Aṣọ n pe aṣọ ran niṣẹ, bẹẹni oriṣiriṣi ijo ati afihan aṣa Yoruba naa ko gbẹhin nibi iwuye naaÀkọlé àwòrán, Sultan ilu Sokoto, Muhammadu Sa'ad Abubakar, naa ba wọn kopa nibi ayẹyẹ nla naaÀkọlé àwòrán, Awọn ọba alade naa ko gbẹyin nibi iwuye ọhun. Lara awọn oriade to tun peju sibẹ ni Soun ti Ogbomoso, Ọba Ghandi OlaoyeÀkọlé àwòrán, Alaaafin tuntun, Oba Abimbola Akeem Owoade I ree, to gunwa ninu ọla nla rẹ gẹgẹ bi ọbaÀkọlé àwòrán, Alaafin Owoade ati olori rẹ, Ayaba Abiwumi OwoadeÀkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ilu ilẹ Yoruba ni wọn lu nibi ayẹyẹ naaÀkọlé àwòrán, Iṣọkan dun pupọ! Olori awọn ẹya Igbo nilẹ Yoruba, naa ba wọn peju sibi ayẹyẹ iwuye naaÀkọlé àwòrán, Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon naa ba wọn kopa nibi ayẹyẹ nla naaÀkọlé àwòrán, Oluwo ti Iwo, Oba Abdurasheed Akanbi naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ manigbagbe ọhunÀkọlé àwòrán, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams. Alaafin to waja laipẹ yii, Ọba Lamidi Adeyemi III, lo fi jẹ oye naa