Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Aláàfin tuntun sọ lẹ́yìn tó gba ọ̀pá àṣẹ

Aworan Alaafin tuntun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaafin ikẹrindinladọta niluu Ọyọ, Ọba Abimbọla Akeem Ọwọade 1 ti gun ori apere gẹgẹ bii ọba tuntun niluu Ọyọ.

Nibi akanṣe ayẹyẹ iwuye to waye ninu ọgba ile ẹkọ girama 'Olivet High School' to n bẹ niluu Ọyọ ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti fi idi gbigbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri a-yan-ọ-sipo fun ọba tuntun naa mulẹ.

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipejọpọ naa, Makinde ni lati ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun yii ti oun ti fun Alaafin tuntun ni ọpa aṣẹ ati iwe ẹri ni ọfisi oun to n bẹ niluu Ibadan ni oun ti yan ọba tuntun.

Ayẹyẹ iwuye oni kan kin igbesẹ naa lẹyin ni.

Makinde ni ki gbogbo ẹnikẹni to ba ṣi n fi apa janu wi pe awọn ko tii gba wi pe ọba tuntun ti jẹ niluu Ọyọ lọ ba Kabiyesi Alaafin tuntun funra wọn.

Ninu ọrọ idupẹ tiẹ, Alaafin tuntun fi idunnu rẹ han gẹgẹ bi o ṣe n dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ṣe atilẹyin fun titi di ọjọ oni.

O ṣe ileri lati maa ṣe atilẹyin fun awọn eeyan ilu gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe atilẹyin fun oun naa.

O parọwa si gbogbo eeyan ilu lati fi agbajọwọ ati iṣokan gbe ilu Ọyọ gun oke agba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọba Ọwọade tẹnu mọ pataki ajọṣepọ laarin ọba ati awọn eeyan ilu nitori eyii yoo fi aye gba ifohunṣọkun ti a fi n yanju iṣoro.

O ni ipese iṣẹ ati idagbosoke eto ọrọ aje naa yoo maa gberu sii nipase ajọṣepọ yii.

Alaafin Ọyọ tuntun fi kun ọrọ rẹ wi pe o to akoko fun gbogbo ọmọ Ọyọ lorilẹede yii ati ni oke okun lati fi agbajọwọ tun ilẹ baba wọn ṣe.

O dupẹ lọwọ Gomina Ṣeyi Makinde ati gbogbo Ọyọmesi fun aṣeyọri iwuye naa.

Ọgọrọ awọn alejo pataki, ladelade ati loyeloye lo peju pesẹ si ibi iwuye naa.

Lara wọn ni Minisita ohun amuṣagbara, Adebayọ Adelabu to ṣoju aarẹ Bọla Tinubu, igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Lawal, igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun Kola Adewusi, aṣoju gomina ipinlẹ Ondo, Olusẹgun Olusegun Omojuwa, Iba Gani Adams, Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, aṣoju Olubadan ilẹ Ibadan, Ṣoun ilẹ Ogbomoṣọ, Ọba Ghandi Laoye, Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, Ọkẹrẹ ilu Ṣaki, Oba Khalid Oyeniyi Ilugbemidepo Olabisi , Asẹyin ilu Isẹyin, Oba Sefiu Oyebola Adeyeri III, Sultan Sokoto, Alhaji Muhammadu Sa'ad Abubakar, Alakoso gbogbo ẹya Igbo nilẹ Yoruba, adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Adebọ Ogundoyin ati igbakeji rẹ. Ọkanojọkan ẹgbẹ awujo naa ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.

Aworan
Aworan