Religion tolerance in Nigeria: Obìnrin Mùsùlùmí ní òun ṣe ilé àlùfà ní ọ̀ṣọ́ kérésì láti polongo ìrẹ́pọ̀

Oríṣun àwòrán, The Cable NG
Ramatu Tijjani, ẹlẹsin Musulumi kan to n gbe ni ipinlẹ Kaduna, ti ṣe ile alufa kan, Mobel Wuye lọṣọ pẹlu 'igi Keresi'.
Tijjani, to jẹ aṣoju ajọ alaafia sọ pe, Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati fihan awọn aladugbo wọn to jẹ Kristiẹni pe, ẹsin alaafia, ifẹ ati ipamọra ni Islam.
O ṣalaye pe oun gbe igbesẹ naa lati polongo alaafia ati irẹpọ, ati lati mu ki alaafia jọba laarin awọn ẹlẹsin mejeeji.
- Ìmáámù tó gbẹ̀mí èèyàn là yóò bọwọ pẹlú Buhari
- Ìpínlẹ̀ Kaduna dá àwọn olùkọ́ tuntun dúró
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, El-Rufai fi ipò míì dá Sanusi lọ́lá
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé oṣù ojú ọ̀run táwọn Mùsùlùmí ń lò ti wà saájú Ànọ́bì?
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tí Amẹ́ríkà fẹ́ gbé lórí Nàìjíríà nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
- Ṣọ́ọ́ṣì kan sí ìlẹ̀kùn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí láti kírun Jímọ̀ ní Germany
"Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati ro ibaṣepọ wọn pẹlu aladugbo to jẹ Kristiẹni. Idi si niyii ti mo fi ma n ya owo sọtọ lati fi ra ounjẹ ati awọn nkan mii, lati pin fun awọn ọrẹ ati ẹbi mi."

Oríṣun àwòrán, The Cable NG
Tijjani sọ pe oun ṣe ile alufa naa ni ọṣọ, lati bu ẹwa kun pẹlu igi, ina, aṣọ ati awọn nkan ẹṣọ mii.
O ni "mo ṣakiyesi pe igi Keresimesi ṣe pataki si gbogbo Kristiẹni kaakiri agbaye, lo jẹ ki n ṣe bẹ ẹ fun alufa, ati lati ki gbogbo Kristiẹni ku ọdun ati imurasilẹ fun ọdun tuntun".
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
- Ọ̀fẹ́ ló bá dé, Boko Haram kọ́ ló jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé, a kò san kọ́bọ̀ fún ìdáǹdè wọn - Masari
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
- Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo
- Ìtura ìgbà díẹ̀ ni bọ́dà tí ìjọba ṣí padà, kò lóòre nínú - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
O ṣalaye pe lati bi ọdun mẹwaa ni oun ti n pin igi Keresimesi fun adari ẹsin Kristiẹni, pẹlu iwoye pe ọrọ ẹsin ati oṣelu ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ ni Naijiria, to si tun n mu ifasẹyin ba alaafia.
Alufa Wuye to fi ẹmi imoore han sọ pe, idunnu ati iyalẹnu ni ẹbun Tijjani jẹ fun oun, nitori pe oun ko gba iru ẹbun bẹ ẹ ri lọwọ obinrin Musulumi.
Bakan naa ni iroyin mii sọ pe obinrin musulumi miran, Hajia Ramatu tun fi igi Keresi se ọsọ ni ile alaga ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN to wa nilu Kaduna, Ẹni-ọwọ Hayap.

Oríṣun àwòrán, Vanguard
Ramatu ni oun naa lo anfaani akoko keresi yii lati tan ọrọ ifẹ, alaafia, irẹpọ ati ipamọra kalẹ ni.
Nigba to n fi ẹmi imoore rẹ han si Hajia Ramatu, Ẹni-ọwọ Hayap mọriri ọwọ ọrẹ naa, to si se apejuwe obinrin musulumi ọhun bii ẹlẹyinju aanu.













