Ogun Police: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ajínigbé ní bi tí wọ́n ti ń gba owó

Oríṣun àwòrán, Others
Ọwọ sinkun ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti tẹ awọn afurasi ajinigbe meji lasiko ti won n gba owo idasilẹ ọmọ ti wọn jigbe.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ọjọ Aiku ni wọn ji ọmọ naa gbe ni agbegbe Agbara nipinlẹ Ogun
Awọn afurasi mejeeji ti ọwọ tẹ naa ni wọn pe orukọ wọn ni Muhammed Abubakar, to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji ati Clinton Niche to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun.
- Kàyééfì! Ẹ wó ìyàwó tó ṣán ọkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó sí fí àdá bẹ orí rẹ̀!
- Ẹ yé kóra jọ pọ̀ láti d'ẹ́rù ba ni pé ọwọ́ Yorùbá ni Ààrẹ 2023 gbọ́dọ̀ bọ́ sí- Shekarau
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp ti yín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé...
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
Lasiko ti agbẹnuso ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun n fi idi ọrọ naa mulẹ, DSP Abimbola Oyeyemi ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lẹyin ti awọn mọlẹbi rẹ fi to awọn ọlọpaa leti.
Gẹgẹ bi ọrọ agbẹnusọ naa, arakunrin Stephen Ajibili to jẹ baba ọmọ ọdun meje ti wọn jigbe, Daniel lo wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.
Agọ ọlọpaa naa wa ni agbegbe Agbara pe awọn ajinigbe ti ji ọmọ oun gbe lọ lasiko ti iya rẹ ran an ni iṣẹ ni nkan bi aago mọkanla aabo ni owurọ ọjọ naa.
Baba ọmọ naa sọ fun awn ọlọpaa pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn ti wọn si beere fun miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo itusilẹ.
''Wẹrẹ ti a gbọ iroyin naa ni awọn ọtẹmuyẹ ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ, ti wọn si lọ si ibi ti awọn ajinigbe naa sọ pe ki wọn wa gbe owo itusilẹ naa si.''

Oríṣun àwòrán, Others
''Bi awọn ajinigbe ṣe n gbiyanju lati gba owo itusilẹ naa ni awọn ọlọpaa ko wọn.''
Lẹyin naa ni wọn mu awọn ọlọpaa lọ si abẹ igi ti wọn sọ ọmọ ọdun mẹwaa ti wọn jigbe naa si.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ifọrwanilẹnuwo jẹ ki wọn mọ pe awọn ajinigbe mẹta lo ṣiṣẹ ibi naa, amọ ti ọkan yoku to duro ti ọmọde naa nigba ti awọn mejeeji lọ gba ọwọ itusilẹ, lo na papa bora bi o ṣe ri awọn ọlọpaa naa.
- Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu
- Àṣírí ọ̀rọ̀ àti dúkìá ìkọ̀kọ̀ ẹbí aarẹ Uhuru Kenyatta tú
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abiodun Alamutu ti paṣẹ ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ẹka to n ṣewadii ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miran.
Bakan naa ni kọmiṣọnna naa paṣẹ ki wọn wa ajinigbe kan to ku to na papa bora naa, ki gbogbo wọn si foju wina ofin.
















