MC Lively: Nítorí pé mo máa ń bínú púpọ̀ nínú àwọn fọ́nrán mi àwọn èèyàn kò mọ̀ pé mo fẹ́ràn láti máa rẹ́rìn ín
Inú ìrírí tí mo rí ni mo ti máa ń rí ìmísí fún àwọn fọ́nrán mi- Mc Lively
Micheal Sanni Amanesi Aluyon Pius to je gbajugbaja alawada gbalejo BBC Yoruba.
O ni egbẹ̀rún márùn ún naira ni owó osù akọ́kọ́ ti òun gba lẹ́nu isẹ́ agbẹjọ́rò kí òun tó kúrò níbẹ̀ yà sí aláwadà báyìí.
Mc Lively salaye pe oun wà láti ipinle Edo ṣùgbọ́n ilẹ̀ Odùduwà, ni Ile Ife ni ipinle Osun ni guusu iwo oorun Naijiria ni wọn bí oun si ti o si dagba nibe.
Eyi lo je ki ede Yoruba dun lenu re pupo.
Mc Lively ni pe: Torí pé mo maa n bínú nínú àwọn fọ́nrán mi ni àwọn èèyàn kò se mọ pe mo fẹ́ràn láti má a rẹrin.
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọlù Russia sí Ukraine àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ Naijiria tó wà níbẹ̀
- Ẹ gbàgbé pé mo lọ gba ìtọ́jú ní London, mo ní ọpọlọ pípé láti tukọ̀ Naijiria - Tinubu
- Kí ni NATO ń ṣe sí ìkọlù Russia sí Ukraine?
- INEC kéde ọjọ́ tí ìdìbò sípò Ààrẹ ọdún 2023 yóò wáyé
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná olówó pọ̀ọ̀kù,wo ọgbọ́n tó dá síi
- Kíni ìkọlù Russia sí Ukraine ń se lórí búrẹ́dí títà àti rírà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀?
- Máṣe sọ tíì eléwé àti kọfí rẹ nù, ó lè sọ ọ́ di olówó
- Ṣé lóòótọ́ làwọn ọ̀dọ́ ìlú Ubiaja dá adigunjalè tó jí owó ní báń

Nibo ni Michael Sanni ti n ri awon awada re gege bii orisun?
Amanesi Aluyon Pius ni pe ẹ̀wà ni ounje ti oun feran julo lati maa jẹ de ibi pe oun lè jẹ ẹ̀wà pẹ̀lú spagetti.
Bakan naa lo salaye fun BBC orisun irir re pe: Inu ìrírí ti mo ri ni mo ti má rí imisi fún àwọn fọ́nrán mi.Mc Lively.
Ninu Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Mc Lively aderinposonu Naijiria yii naa lo tun ti sọ nipa awọn ipenija to ti koju ri lasiko to n wa ise.