Azerbaijan gba àkóso agbègbè Nagorno-Karabakh, ìró ìbọn ń dún lákọlákọ, ọ̀pọ̀ èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn

Àkọlé fídíò, “Gbogbo ìgbà ni ìró ìbọn máa ń dún lákọlákọ, a ní láti sá àsálà fún ẹ̀mí wa”
Azerbaijan gba àkóso agbègbè Nagorno-Karabakh, ìró ìbọn ń dún lákọlákọ, ọ̀pọ̀ èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn

Ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọ orilẹ-ede Armeina lo ti fi agbegbe Nagorno-Karabakh silẹ nitori awọn ikọlu to n waye nibẹ.

Eyii ko ṣẹyin bi orilẹ-ede Azerbaijan ṣe gba iṣakoso agbegbe naa.

Akọroyin BBC to ṣabẹwo si awọn eeyan naa to sa asala fun ẹmi wọn ni ala Armenia ati Nagorno-Karabakh, Nataliya Zotova jabọ pe ọpọ awọn ogunlende naa ni ko ni ireti ati pada silẹ wọn mọ.

Ọkan lara awọn ogunlende ọhun, Alpine Movsyan, ṣalaye fun BBC pe gbogbo igba ni iro ibọn maa n dun lemọlemọ nibẹ.

O ni “Gbogbo igba la maa n gburo ibọn, wọn ko tilẹ dawọ rẹ duro fun iṣẹju marun un pere.”

“O ṣoro fun wa lati sa asala kuro ni ibi ti a sa pamọ si labẹ ile nitori ojiji ni iku le de.”

Kaakiri agbaye ni igbagbọ ti wa pe ara ile Azerbaijan ni Nagorno-Karabakh wa, amọ lati nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ni ilẹ naa ti wa ikawọ ijọba Armenia, ti awọn eeyan to n gbe ibẹ si n padanu ẹmi wọn lọwọ oniruru ija to naa ma waye nibẹ.

Wayi o, olootu ijọba Armenia ti kilọ fun gbogbo awọn to ṣi wa ni Nagorno-Karabakh ki wọn fi agbegbe naa silẹ, bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki ẹmi wọn lọ si.