Ẹ sinmi agbaja, ẹbí Mohbad ló ní ẹ̀tọ́ láti ṣàyẹ̀wò DNA fún ọmọ rẹ̀ - Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Iyabo Ojo ti sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn èèyàn kan ṣe ń pè fún àyẹ̀wò DNA fún ọmọ Mohbad.
Àwọn èèyàn náà ló kéde pé ó yẹ kí wọn ṣe àyẹ̀wò DNA láti mọ̀ bóyá ọmọ bíbí Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Mohbad gangan ni Liam tí òun àti ìyàwó rẹ̀, Omowunmi bí papọ̀ kó tó jáde láyé.
Àmọ́ Iyabo Ojo, nínú fídíò kan tó ṣe lójú òpò Instagram rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ náà kò kan ẹnikẹ́ni àyàfi àwọn ẹbí Mohbad nìkan.
Iyabo Ojo ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ń kọ àtẹ̀jíṣẹ́ sí òun pé kí àwọn fi àyẹ̀wò náà kún ohun tí àwọn ń jà fún lórí ikú Mohbad.
"Tí òbí Mohbad bá fẹ́ mọ̀ bóyá ọmọ àwọn gangan ló ni ọmọ, wọ́n máa ṣe DNA fún ara wọn"
Ó ní òun fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹbí ni irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ jẹ́ àti pé tí àwọn òbí Mohbad bá fẹ́ àyẹ̀wò ọ̀hún, àwọn ni wọ́n máa ṣe fún ara wọn.
"Mohbad kò fi ìgbà kankan sọ pé Liam kìí ṣe ọmọ òun nígbà tó wà láyé nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe sọ pé kí àwọn ṣe àyẹ̀wò náà.
Tí àwọn òbí Mohbad bá ri pé àwọn nílò láti ṣe àyẹ̀wò bóyá ọmọ àwọn gangan ló ni ọmọ, wọ́n máa ṣe fún ara wọn."
Ẹ ó rántí pé láti ìgbà tí olórin tàkasúfèé náà, Mohbad jáde láyé lọ́jọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń pè fún ìwádìí lórí ikú rẹ̀.
Bákan náà ni àwọn mìíràn ń fẹ̀sùn kàn ìyàwó Mohbad Omowunmi pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ọkọ rẹ̀ àti pé ó yẹ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mohbad ló bí Liam fún ní tòótọ́.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"A kò tí ì lè nàka àléébù sí ẹnikẹ́ni lórí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad"
Iyabo Ojo wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fi àwọn ẹbí Mohbad sílẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọ wọn nínú ìfọ̀kànbalẹ̀ nítorí ohun tó lágbára ni ikú ọmọ.
Ó ní òun ní ìdánilójú pé àwọn máa rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú rẹ̀ àmọ́ kí àwọn ènìyàn sinmi láti gbé àwọn ìròyìn tó lè ṣi àwọn lọ́nà lórí àwọn ìwádìí tí àwọn ń ṣe.
Bákan náà ló gba àwọn ènìyàn ní ọ̀ràn láti ṣe sùúrù gidi kí èsì àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún òkú Mohbad fi jáde.
Ó ní ó kéré tán ó máa ń tó ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kí èsì àyẹ̀wò náà tó jáde àti pé àwọn kò nílò ohunkóhun tó le gbé ọkàn àwọn kúrò nínú wíwá ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ náà.
Ó ní ìwádìí àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lórí ikú Mohbad ló ti ń lọ́wọ́.
Ó fi kun pé àwọn kò ì tíì lè nàka àléébù sí ẹnikẹ́ni lórí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad àyàfi tí àwọn ọlọ́pàá bá parí iṣẹ́ wọn tí wọ́n sì mú ẹnìkan jáde pé ó jẹ̀bi.
Liam kìí ṣe ọmọ Mohbad, ó pọn dandan láti ṣe àyẹ̀wò DNA - Kemi Olunloyo
Ṣáájú ni gbajúmọ̀ akọ̀ròyìn, Kemi Olunloyo ti fẹ̀sùn kàn pé ìyàwó Mohbad, Omowunmi ti ṣe àyẹ̀wò DNA kan sẹ́yìn tí ìwádìí náà sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Sam Larry ló bí Liam, pé kìí ṣe Mohbad ló ni ọmọ náà.
Kemi Olunloyo ni àwọn ìwádìí tí òun ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Liam kìí ṣe ọmọ bíbí Mohbad.
Ó ní ó pọn dandan láti ṣe àyẹ̀wò DNA nítorí ó hàn gbangba pé kìí ṣe ọ̀rọ̀ pé Mohbad fi iléeṣẹ́ orin Marlian Music sílẹ̀ nìkan ló bí ìjà láàárín Mohbad àti Sam Larry.Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni Omowunmi ti ń rán sí òun pé kí òun má fi èsì àyẹ̀wò DNA tí òun ní lọ́wọ́ síta.
Ó ṣàlàyé Mohbad ti ṣàyẹ̀wò náà kí ó tó jáde láyé tó sì ti mọ̀ pé òun kọ́ ni òun bí Liam àti pé nítorí náà ni wọ́n ṣe pa Mohbad.
"Mohbad ti ṣe àyẹ̀wò DNA ní Dubai tó sì ti mọ̀ pé òun kọ́ ni òun bí Liam ṣùgbọ́n ó ṣe ọ̀rọ̀ náà ní òkú òru."
Mi ò lọ́wọ́ nínú ikú Mohbad, kìí ṣe nǹkan àjèjì pé ìjà wàyé – Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Naira marley/Mohbad
Oludasilẹ ileeṣẹ Marlian Music, Azeez Fashola ‘Naira Marley’ ti sọrọ fun igba akọkọ lori ẹsun lilọwọ ninu iku oloogbe Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad.
Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ ni Naira Marly ti sọ pe oun ti ṣetan lati ṣeranlọwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lọna ati tu iṣu de isalẹ ikoko ohun to ṣokunfa iku Mohbad.
Atẹjade yii lo n waye lẹyin nnnkan bii ọsẹ meji ti Mohbad jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn niluu Eko.
Ṣaaju ni awọn mọlẹbi Mohbad ti kọkọ lọ palẹ oku rẹ mọ amọ ariwo awọn araalu mu ki ileeṣe ọlọpa gbe igbesẹ lati lọ wu oku naa fun ayẹwọ lọna ti mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Lọṣẹ to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede pe oun ti pari ayẹwo oku Mohbad, ti esi iwadii wọn rẹ yoo si jade laipẹ.
Ki ni Naira Marley sọ?
Ninu atẹjade to fi lede, Naira Marley sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa iku Mohbad, bẹẹni oun ko lọwọ ninu iku rẹ.
O ni “Ẹ jẹ ki n ṣọ ni gbangba bayii pe mi o lọwọ ninu iku Mohbad, yala lati ọwọ mi ni o tabi lati ọwọ ẹlomiran to jẹ nipasẹ mi.”
“Kii ṣe ohun ajoji ninu iṣẹ wa, bo ṣe wa ninu awọn ẹka iṣe mii, pe ija maa n waye, koda ija maa n waye laarin ọmọ iya pẹlu.”
O sọ siwaju si pe iku ọdọmọde olorin naa dun oun gẹgẹ bo ṣe dun ọpọ araalu.

Oríṣun àwòrán, naira marley

Oríṣun àwòrán, naira marley
“Ọlọpaa ti fiwe pe mi, mo ti ṣetan lati ran iwadii ọlọpaa lọwọ”
Naira Marley fi kun pe eredi ti oun ko ṣe sọ ohunkohun lati igba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ ni pe oun ko fẹ ṣakoba fun iwadii to n lọ lọwọ pẹlu ọrọ ti oun ba sọ.
Marley ni “Lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni mi o ti si Naijiria, mi o si tii pada.”
“Ni bayii ti ọlọpaa ti fi iwe pe mi, mo ti ṣetan lati pada wale lati ran iwadii ọlọpaa lọwọ ki n si ṣalaye ohun ti oju mi ri nipa iṣẹlẹ naa.”
"Mi o kii ṣe baba isalẹ awọn to n gbe oogun oloro, bẹẹ ni emi Marley, ko si ninu ẹgbẹ okunkun tabi ẹgbẹ imulẹ kankan"
“Mi o sa fun iwadii ọlọpaa nitori mi o lọwọ ninu iku rẹ mi o si le di isansa nitori ọrọ yii.”
Nipa ti gbigbe oogun oloro, Naira Marley ni irọ ni awọn iroyin oogun ti awọn eeyan n gbe kiri nipa oun.
O ni “Mi o kii ṣe baba isalẹ awọn to n gbe oogun oloro, bẹẹni emi Marley, ko si ninu ẹgbẹ okunkun tabi ẹgbẹ imulẹ kankan.
“Mo ti ṣetan lati jẹ lati ki araye mọ pe mi lọwọ ninu iku rẹ, ileeṣe wa kii sii ṣe ohun to ba lodi si ofin.”
















