Afcon 2023: Mọ àsìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àti ìròyìn míì nípa àgbábọ́ọ̀lù bí Salah, Andre Onana, Osimhen, Mane

Awọn ikọ ti yoo kopa ninu idije Afcon ọdun 2023 ni o ti di mimọ bayii amọ ṣe iwọ mọ igba ti idije naa yoo gberasọ ni Ivory Coast ati ipa ti yoo ni lara awọn agbabọọlu Africa to n ṣowo ere boolu nidije Premier Liigi ati ibomiran lagbaye?
Fun asiko to sunmọ oṣu kan gbako lawọn gbaugbaja agbabọọlu yoo maa gbiyanju lati jaweolubori ninu idije ẹlẹẹmeeji lọdun Afcon ti ajọ ere bọọlu Africa Caf ṣe agbatẹru rẹ.
Senegal to ṣe pe awọn lo gba ife naa kọja yoo kan si awọn atamatase wọn bi Sadio Mane to n ṣoju fun ikọ Al Nass ati agbawaju Chelsea nii Nicolas Jackson.
Egypt,to ti gba ife naa ni ẹmeeje ọtọọtọ yoo lanfaani balogun wọn nii Mohammmed Salah to n gba fun Liverpool.
Ki idije naa to bẹrẹ, diẹ ree lara awọn nkan to yẹ ni mimọ nipa asiko ifẹsẹwọnsẹ,ipin isọri kọọkan ati awọn agbabọọlu to ṣeeṣe ki wọn ma kopa nibi idije abẹle.
Nigba wo ni Afcon 2023 yoo waye?
Abala ikẹrinlelọgbọn Afcon yoo bẹrẹ ni ọjọ Kẹtala oṣu Kini titi di ọjọ kọkanla oṣu Keji 2024.
Igba keji ree ti Ivory Coast yoo ṣagbatẹru idije naa.Saaju wọn gbalejo rẹ lọdun 1984.
Laarin oṣu kẹfa si oju keje ọdun 2023 lo yẹ ki idije yi waye amọ ibẹru ṣiṣe idije yi lasiko ojo lo mu ki wọn sunjọ rẹ siwaju si.
Tohun ti pe ọdun 2024 ni yoo waye, wọn yoo si pe akọle idije naa ni Afcon 2023.
Orileede Ivory Coast ni yoo ṣide idije naa ti wọn yoo si koju kan lara awọn orileede mii to ba wa ni isọri kini pẹlu wọn.
Awọn ikọ meji to ba lewaju ni isọri kọọkan ati awọn mẹrin mii to ba ṣe daada ni ipo kẹta ninu awọn isọri mẹfa to jijọ pilẹ idije naa ni yoo tẹsiwaju lọ abala ikọ mẹrindinlogun, komẹsẹoyọ, abala to kangun si aṣekagba, abala onipo kẹẹta ati aba aṣekagba idije naa.
Papa iṣere nla Alassane Outtara ni olu ilu ilẹ naa Abdijan ni yoo gbalejo abala aṣekagba idije naa lọjọ Kọkanla oṣu keji 2024.

Ki lo ṣẹlẹ lawọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi mu awọn ti yoo kopa ninu idije Afcon 2023?
Igbakẹta ree ti awọn orileede mẹrinlelogun yoo kopa ninu idije naa lẹyin ti wọn fẹ ẹ iye oludije loju si lọdun 2019.
Tohun ti pe Ivory Coast lo gbalejo idije naa wọn yi kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fipegede lati kopa.
Ipo keji ni wọn ṣe lẹyin Zambia tolewajuni isọri H.
Awọn ikọ mejilelogun mii ni yoo darapo mọ wọn.
Gbogbo awọn to n kopa ninu idije yi lọdun yi lo ti kopa ri o kere tan lẹẹmeejitẹlẹ ri ayafi Zambia to jaweolubori ni dun 2015.
Igba akọkọ ree ti wọn yoo maa kopa pada lati igba naa.
Mozambique yoo maa kopa ni igba ẹlẹkaarun,alakọkọ iru rẹ lẹyin dun 2010 ti wọn kopa kẹyin.
Diẹ lo ku ki Central African Republic fi itan lelẹ ni igba akọkọ ti wọn yoo kopa amọ Ghana yẹ aga mọ wọn nidi ni ifẹsẹwọnsẹ ikẹyin ti wọn jijọ gba.
Gabon to jẹ orileede ti Pierre-Emerick Aubameyang ti wa ni orileede ilumọọka to padanu anfaani lati kopa.
Ninu idije mẹrin to waye kẹyin,wọn kopa ninu mẹta ninu wọn.
Nigba wo ni wọn yoo pin ikọ kọọkan si isọri ati pe ba wo lo ṣe n lọ?
Ọjọ kejila oṣu kẹwaa ni wọn yoo ṣeto pinpin awọn ikọ kọọkan si isọri.
Yoo waye ni Abidjan laago meje alẹ.
Bi a ba fi alakalẹ akasọ orileede kọọkan lati ọwọ Fifa wo,inu koto mẹrin ni wọn yoo ko orukọ awọn olukopa si.
Ivory Coast to jẹ pe ipo kẹsan ni wọn wa nilẹ Afrika yoo ba wọn wa ninu koto alakọkọ.
Bayi ni wọn yoo ṣe to awọn orileede to n kopa si ninu koto kọọkan.
POT ONE - Ivory Coast (*50), Morocco (13), Senegal (20), Tunisia (29), Algeria (34), Egypt (35)
POT TWO - Nigeria (40), Cameroon (41), Mali (49), Burkina Faso (58), Ghana (60), DR Congo (64)
POT THREE - South Africa (65), Cape Verde (71), Guinea (81), Zambia (82), Equatorial Guinea (92), Mauritania (99)
POT FOUR - Guinea-Bissau (106), Mozambique (113), Namibia (114), Angola (117), The Gambia (118), Tanzania (122)
Wọn yoo pin awọn ikọ wọnyi si isọri mẹfa.Ikọ mẹrin ni yoo wa ni inu isọri kọọkan.
Saaju ki idije to bẹrẹ ni wọn yoo ti ya aaye sọtọ fun orileede kọọkan.
Wọn o ni ti fi iroyin nipa eleyi sita bayii.
Papa iṣere mẹfa ni wọn yoo lo lasiko idije yi:
Alassane Ouattara Stadium, Abidjan to gba eeyan 60,000
Felix Houphouet Boigny Stadium, Abidjanto gba eeyan 33,000)
Stade de la Paix, Bouaketo gba ero 40,000
Amadou Gon Coulibaly Stadium, Korhogo to gba ero 20,000
Laurent Pokou Stadium, San Pedro to gba ero 20,000
Charles Konan Banny Stadium, Yamoussoukro to gba ero 20,000
Caf a maa saba pe awọn irawọ ilumọọka ere bọọlu lati wa foju han lasiko ti wọn n pin awọn ikọ si isọri fun idije Afcon
Tori naa o ṣeeṣe ki ẹ foju ri awọn agbaọjẹ agbabọọlu bi Kolo ati Yaya Toure.
Ọmọ Ivory Coast lawọn mejeeji ti wọn si ti kopa kọja ninu idije Afcon ti Ivory Coast ti gba ife ẹlẹẹkeji lẹyin ti wọn fidi Ghana rẹmi ni Ivory Coast lọdun 2015.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba wo lawọn agbabọọlu Premier Liigi yoo ribi gba isinmi?
Eyi ni itọka afojusun iye ọjọ ti awọn agbabọọlu Premier Liigi ko fi ni ribi kopa nitori idije liigi tabi awọn idije mii bi FA Cup.
Asiko isinmi otutu Winter: 15-28 oṣu Kini
Awọn asiko ifẹsẹwọnsẹ ikọ liigi wọn: Opin ọsẹ January6/7 ti wọn yoo gba abala kẹta idije FA Cup.
O kere tan wọnko ni le kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu Premier Liigi
O wa pọju, wọn yoo padanu ikopa ninu ifẹ́sẹwọnsẹ mẹrin(ifẹsẹwọnsẹ liigi mẹrin,FA Cup ipele kẹrin,Idije abala to kangun si aṣekagba Carabao Cup,Abala ikọ mẹrindinlogun ti Champions Liigi)
O ṣeeṣe ki wọn tun gba awọn ifẹsẹwọnsẹ mii bi abala keji naa lasiko taa n wi yi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idiwọ to le waye ni Liigi Saudi
Isinmi asiko otutu Winter:29 December - 14 February
Aṣekagba ifẹsẹwọnsẹ ikẹyin liigi: 28 December (Pro League)
O kere tan iye ifẹsẹwọnsẹ ti wọn le padanu: Ko si ikankan ti wọn yoo padanu
O pọju niye ifẹsẹwọnsẹ ti wọn le padanu kikopa:Mẹta ninu Saudi Super Cup semi-finals ati final, Asian Champions League abala ikọ mẹrindinlogun apa kini.
Ọjọ ti o ṣeeṣe ki agbabọọlu pada: ifẹsẹwọnsẹ Saudi Super Cup loṣu Kini(group ati lọjọ KLẹtadinlogun oṣu Keji
Seria A ni Italy

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Isinmi asiko otutu Winter: Ko si
Awọn ọjọ ifẹsẹwọnsẹ ikẹyin ni Liigi: Ipari ọsẹ ọjọ kẹfa ati ikeeje oṣu Kini ninu idije Serie A
Iye ifẹsẹwọnsẹ to kere ju ti wọn le padanu: Meji ni Serie A
Iye ifẹsẹwọnsẹ to pọju ti wọn le padanu: Mọkanla (Serie A mẹfaa, Abala to kangun si aṣekagba ati abala aṣekagba Supercoppa Italiana, Abala onikọ mẹrindinlogun Coppa Italia ati abala komẹsẹoyọ Champions Liigi















