Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni àwọn ajínigbé tó jí akọrin 20 gbé n béèrè fún - ìjọ CAC

Ijọ CAC Oke Igan

Awọn ọmọ ijọ CAC Oke Igan nilu Akure to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo ni wọn ti bẹrẹ adura ni kikan latari awọn akọrin ijọ naa tawọn ajinigbe ko lọ.

Abẹwo akọroyin BBC Yoruba sile ijọsin naa laarọ ọjọ Abamẹta lo fihan pe gbogbo ọmọ ijọ naa peju lati rawọ ẹbẹ si Ọlọrun lori itusilẹ awọn ti wọn ji gbe ọhun.

Lati ita ile ijọsin naa ni ariwo adura naa ti n dun lakọlakọ.

Adari ijọ naa, alufaa Benjamin Akanmu, to jẹ alakoso ijọ CAC ni ẹkun Odubanjo wi pe, ilu Ifọn ni awọn akọrin naa n lọ fun aṣalẹ onigbagbọ fun eto isinku baba to bi aladura ijọ wọn to doloogbe.

O ṣalaye pe ni ọjọ Ẹti ni wọn gbera kuro nilu Akure to si yẹ ki wọn pada de lọjọ Abamẹta lẹyin isinku.

“Ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Ẹti ni ẹnikan pe mi pe oun ri ọkọ ijọ wa lẹba ọna lagbeegbe Ẹlẹgbẹka ti ko si si enikẹni ninu rẹ.

“Ọkunrin naa ni ko ma jẹ pe awọn ajinigbe lo ko wọn lọ, baa ṣe bẹrẹ si nii pe awọn eeyan wa atawọn agbofinro niyẹn.”

O ni ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa to ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa ti pe, to si ni aadọta miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa n beere fun lati tu awọn silẹ.

“Bi o ṣe n bami sọrọ lọ ni ọkan ninu awọn ajinigbe naa gba foonu to si ni ki n lọ wa aadọta miliọnu naira ni kia ti mo ba nifẹ awọn eeyan mi.

O ni awọn mẹsan-an lo ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa bayii bi awọn mẹjọ ṣe ti gba itusilẹ amọ awọn ko mọ bi awọn mẹta to ku ṣe rin.

“Igbagbọ wa ni pe Oluwa lo le ṣohun gbogbo, idi ni yi taa fi sa tọ Oluwa wa nitori a ko ni ẹlomiran lẹyin rẹ, a si ti bẹrẹ adura lati ana.

“Mo nigbagbọ pe Oluwa yoo ran awọn agbofinro lọwọ lati le doola ẹmi awọn mẹsan-an to ku ki wọn si tun fi ṣikun ofin mu awọn to ṣiṣẹ laabi naa.”

Àwọn ajínigbé jí ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì CAC l’Ondo lọ, mẹ́jọ nínú wọn ti móríbọ́

Aworan ṣọọṣi CAC l'Ondo

Awọn afunrasi ajinigbe ti ṣọṣẹ ni ipinle Ondo bi wọn ti ṣe ko awọn akọrin to le ni ogun lati ijọ CAC Oke Igan to wa ni ilu Akure.

Ohun ti a gbọ ni pe awon akọrin ọun ni awọn agbebọn ji gbe ni nkan bii aago mẹta ọsan lọjọ Ẹti bi wọn ṣe n rinrin ajo lọsi ilu Ifon ni ijoba ibile Ọsẹ fun ayẹyẹ ìsìnkú obi ọkan lara awon akọrin naa.

Ọmọ ijọ ọun kan to sọrọ labẹ aṣọ wi pe ọkọ to n gbe awọn akọrin naa lọ ni awọn ba nibi ti wọn paati si lẹba ọna.

Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ wi pe igbiyanju ati doola awọn eniyan ọun ti bẹrẹ.

Odunlami-Omisanya ṣalaye pe “ọsan ana ni wọn fi to ajọ ọlọpaa leti pe ọkọ bọọsi ti wọn kọ CAC si lara ni wọn wa pati si agbeegbe Elegbeka, ti wọn si funra si pe awọn ero inu ọkọ naa ni wọn ji gbe lọ.

“Nibayi, ikọ ajọ ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe ati awọn ikọ miran ni wọn ti n wa ọna lati gba awọn ti wọn jigbe naa pada pẹlu igbiyanju lati mu awọn to lọwọ ninu iwa ọdaran naa.”

Aworan ọkọ ṣọọṣi CAC l'Ondo
Aworan ọkọ ṣọọṣi CAC l'Ondo

Mẹ́jọ nínú àwọn akọrin tí wọ́n jígbé ti móríbọ́

Mẹjọ ninu awọn akọrin ijọ CAC, Oke Igan nilu Akure ti wọn jigbe nijọba ibilẹ Ose ni wọn ti gbominira.

Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omosanya to sọ eleyi fawọn akọroyin nilu Akure wi pe awọn mẹjọ naa ni awọn agbofin ro doola ẹmi wọn.

Odunlami-Omosanya fi kun pe awọn ti wọn ti ri gba ọun ṣee lalaye pe awọn n lọ ibi aisun alẹ onigbagbọ ni ti wọn fi kagbako awọn ajinigbe lọna.

“Wọn ni awọn agbebọn marun ni wọn dabu ọna ti wọn si fi ibọn dari awọn wọ igbo lọ ki awọn agbofinro too de.

“Igbiyanju lati doola ẹmi awọn to ku lai fi ara pa lo ṣi n tẹsiwaju,” agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.