Ọlọ́pàá èwo ni tèpè! Ìyá ẹni ọdún 70 fèpè ránṣẹ́ sí àwọn tó jẹun ọjọ́ ìbí rẹ̀ láì ra aṣọ

Oríṣun àwòrán, Toyin Bucknor
Obinrin ẹni aadọrin ọdun kan, Toyin Bucknor, ti di gbajumọ ojiji lori ayelujara lẹyin to gbe awọn awọn eeyan kan to wa nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ṣepe latari pe wọn ko ra aṣọ ẹbi niluu London.
Fidio iṣẹlẹ naa ti gba ori ayelujara kan lẹyin ti apakan awọn alejo to yọju sibi ayẹyẹ naa binu jade ninu gbọgan ayẹyẹyẹ ọhun.
Ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi naa waye.
Ki lo fa awuywuye naa?
Gẹgẹ bii fidio ti a ri, wahala naa ko ṣẹyin aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn mu fun ayẹyẹ ọhun ti awọn eeyan kan ko wọ ninu gbọgan ayẹyẹ ọhun.
Ninu fidio naa, ti ọpọ eeyan ti wo bayii ni obinri ọhun ti n ṣe epe fun awọn to wa nibi ayẹyẹ naa amọ ti wọn ko ra aṣọ ti wọn mu fun ayẹyẹ naa.
O ni “Aṣẹ ni mo fi n sọrọ... ẹni ti ko ba wọ aṣọ mi, ti ko gba aṣọ lọwọ mi, to ba kan joko, ibinu ni mo fi n sọrọ, to ba jẹun a gba imu ẹ yọ.”
“Ẹnikẹni ti ko ba gba aṣọ ki wọn jade, maa gbe wọn jade fun ra mi, ẹ ma mu inu bi mi.”
Arabinrin Bucknor ni ẹnikẹni to ba wa ninu gbọgan naa lai ra aṣọ ti wọn ya sọtọ fun ayẹyẹ ọhun gbodọ jade sita, ayafi ti irufẹ ẹni bẹẹ ko ba fẹ pe aadọrin ọdun laye.
Ọpọ awọn to wo fidio iṣẹlẹ naa lo koro oju si ohun ti Bucknor ṣe.
Ikilọ ti waye ṣaaju ayẹyẹ ọjọ ibi naa

Oríṣun àwòrán, @fatitellgistbackup
Ṣaaju ki iṣẹlẹ yii to waye ni ọlọjọ ibi ọhun ti kilọ pe ki ẹnikẹni ti wọn ko ba fi iwe pe ma ṣe yọju sibi ayẹyẹ naa.
Ninu iwe to fi pe awọn eeyan sibi ayẹyẹ ọhun lo fi awọn ikilọ naa si.
Lara awọn ikilọ naa ni pe ki olukuluku ra aṣọ tirẹ, ki awọn eeyan ma si pin aṣọ ti wọn ba ra.
O tun kilọ pe ẹni ti ko ba ni kaadi iwe ipe ko ni wọle, ati pe ki ẹnikẹni ti orukọ rẹ ko ba si lori ijoko maṣe joko sori aga nitori awọn ti oun ba fi iwe pe nikan ni o gbọdọ yọju.
Bucknor tọrọ aforijin
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọlọjọ ibi ọhun tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan.
O ni “Ayẹyẹ yii sọ mi lẹnu pupọ nitori pe mo ti leri, awọn ẹlomii bu mi pe nitori pe mo ti ṣiṣẹ ologun ri ni Naijiria ni.”
“Ẹ ma binu, nnkan to ṣe dun mi ni pe aimoye ti mo da owo ẹ pada... awọn kan ti ba mi leri pe dandan awọn maa wa, awọn ni mo ri ti inu fi bi mi.”
“Ẹ jọọ, ẹ ma binu.. ẹ o ni ku o, nkankan ko ni ṣe yin, ko ni ṣe ọmọ yin.
“Ẹ o wọ ọgọrinn ọdun, aadọrin ati ọgọrun ọdun laye, ajọṣe wa ko ni bajẹ, ẹ ko ni gbọmọ sin.”












