Fifa mú orílẹ̀èdè mẹ́jọ lorílẹ̀ mẹ́ta láti gbàlejò ìdíje àgbáyé ọdún 2030

Awọran Messi atawọn agbabọọlu Argentina kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ agbaye mẹta ọtọọtọ ni idije ife ẹyẹ bọọlu lagbaye yoo ti waye lọdun 2030.

Ajọ to n mojuto ọrọ bọọlu lagbaye iyẹn Fifa lo fidi ọrọ yi mulẹ pe orileede mẹfa ni yoo gbalejo idije yi.

Spain Portugal ati Morocco ni wọn kede pe yoo jijọ gbalejo idije naa.

Awọn ifẹsẹwọnsẹ mẹta akọkọ yoo waye ni Uruguay,Argentina ati Paraguay.

Awọn idije mẹta yi la gbọ pe wọn fẹ fi ṣe ayajọ ọgọrun ọdun ti idije naa bẹrẹ ni Montevideo.

Ipade igbimọ alaṣẹ Fifa yoo buwọlu ipinnu yi lọdun to n bọ.

Bẹẹ naa ni Fifa fidi rẹ mulẹ pe awọn gba iwe mo ṣetan lati gbalejo idije naa lati ọdọ awọn ẹka igbimọ ere bọọlu Asia ati ipe awọn yoo ṣagbeyẹwọ Oceania fun gbigba alejo idije ọdun 2034.

Lẹyin ikede yi ni Saudi naa kede pe awọn yoo fi orukọ silẹ lati du ipo gbigbalejo idije ọdun 2034 fun igba akọkọ.

Ọjọ kọkanlelọgbọn ni gbedeke fifi erongba silẹ lati gbalejo idije yi yoo wa sopin.

Awọn kan bẹnu atẹ lu ikede Fifa lati gbe igbalejo idije yi lọ si ọpọ orilẹ.

Ọkan lara awọn ẹgbẹ alatilẹyin ere bọọlu sọ pe ''Fifa n gbe igbesẹ lati pa ere idaraya to lamilaaka julọ lagbaye run''

Ẹgbẹ alatilẹyin Yuroopu sọ pe ''ohun ti ko bojumu ni fawọn alatilẹyin ere bọọlu ni bi Fifa ṣe fẹ faaye gba orilẹẹde ti ko lorukọ gidi nidi ifaaye gba ẹtọmọniyan ko loun fẹ gbalejo idije ọdun 2034.''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ Aarẹ Fifa Gianni Infantino sọ pe ''nile aye ti ipinya pọ yi, Fifa ati ere bọọlu lo n mu isọkan wa''

O tẹsiwaju pe ''Igbimọ Fifa to n ṣoju ere bọọlu lagbaye panupọ lati ṣe ajọyọ ajọdun ọgọrun idije World Cup ti wọn gbalejo rẹ ni Uruguay lọdun 1930 lọna to bojumu julọ''

''Ni 2030 ọna mẹta ni ao ti ri ipasẹ idije yi-Afrika,Yuroopu ati South Amẹrika-orileede mẹfa Argentina,Morocco,Paraguay,Portugal,Spain ati Uruguay ni yoo gbalejo agbaye lati se ayẹyẹ ọgọrun ọdun idije World Cup lọna ara to yatọ''

Montevideo ni Uruguay to jẹ ibi ti idije akọkọ ti waye yoo gbalejo ifẹsẹwọnsẹ iṣide naa ni ọdun 2030 ti wọn yoo si gba awọn ifẹsẹwọnsẹ mii ni Argentina ati Paraguay.

Eyi to ku ninu idije olorileede mejidinlaadọta yi yoo tẹsiwaju ni ariwa Africa ati Yuroopu.

Iyipada orilẹ yi tunmọ si pe ikọ to n kopa le kopa ni ayika meji ọtọọtọ ninu idije kan ṣoṣo.

Ninu aba ọdun 2030 yi, Morocco yoo jẹ orileede keji ti yoo gbalejo idije yi fun igba akọkọ lati ilẹ Afrika lẹyin South Africa to gbalejo rẹ lọdun 2010.

Wọn kede Spain naa pe wọn yoo jumọ gbalejo idije naa.

Ikede yi waye lẹyin ọsẹ meloo kan ti adari ere bọọlu Spain kọwe fipo silẹ lori ẹsun pe o fẹnuko obinrin agbabọọlu Jenni Hermoso lẹnu lasiko idije ere bọọlu agbaye awọn obinrin..

Ọdun 1982 ni wọn gbalejo idije yi kẹyin ti Italy ṣi pegede ninu idije ọhun pẹlu bi wọn ṣe gbe ife ẹyẹ agbaye ni igba ẹkẹẹta.

Gbogbo awọn to n gbalejo idije yi ni yoo lanfaani lati kopa iyẹn Uruguay, Argentina, Paraguay, Spain, Portugal ati Morocco.

Ọrọ ifarajin Fifa lori ọrọ iyipada oju ọjọ naa tun jẹyọ pẹlu ikede yi

Ipinnu Fifa lati gbalejo idije lọpọ orilẹ n waye lẹyin ti wọn ko sọ ootọ nipa mimu adinku ba ipa ti idije agbaye yoo ni lori ayika wa ni paapa idije Qatar.

Fifa sọ nigba naa pe idije yi yoo yatọ nipa mimu adinku ba iye afẹfẹ gaasi to le ṣe ipalara fun ayika amọ wọn o fi ẹri kankan pẹlu ọrọ wọn.

Losu Kọkanla ọdun ni BBC gbe iroyin tawọn onimọ nipa ayika ti sọ pe ọrọ to le si araalu lọna ni Fifa sọ ti wọn si kilo pe o ṣeeṣe ki ipalara ti idije yi mu ba ayika ṣẹlẹ ni ilọpo mẹta.

Freddie Daley oniwadii ni Global Economy Policy ti Fasiti Sussex, sọ pe ipinnu lati gbalejo idije yi lorilẹ mẹta yoo ni ipalara tori awọn agbagbọọlu,alatilẹyin ati ololufẹ ere bọọlu yoo rinrinajo lorilẹ mẹta dipo ẹyọkan.

O ni ''Mo gbagbọ pe igbesẹ Fifa fi han pe wọn ko jẹ olootọ nipa nkan ti wọn pinnu lati ṣe lori ọrọ iyipada oju ọjọ ati gbigbe igbesẹ lori rẹ.''

O tẹsiwaju pe Fifa lojuṣe lati se idanilẹkọ fawọn eeyan ki wọn si ri pe wọn jẹ ki wọn kopa nibi irinajo idije yi pẹlu ipalara to kere julọ fayika wa.

Saudi Arabia fẹ gbalejo idije ọdun 2034

Ọrọ Saudi to fẹ gbalejo idije ọdun 2034 wa ni ibamu pẹlu ipinnu rẹ lati lewaju nibi ere idaraya lagbaye.

Bi wọn ṣe n ṣagbatẹru idije ere bọọlu ni wọn n ṣe ti Formula 1,Golf ati ẹsẹ jija.

Amọ awọn alatako sọ pe niṣe ni Saudi n fi owo rẹ ati ere idaraya ṣe afọmọ lati wa ojurere lagbaye.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to waye laipẹ yi pẹlu ileeṣẹ iroyi Fox News, ọmọ ọba Saudi Mohammed bin Salman sọ pe ko si ohun to kan oun pẹlu gbogbo ẹsun wọnyi.

O ni ti ''lilo ere idaraya lati ṣe afọmo yoo mu ki owo taa n pa wọle le kun si a o ni jawọ lati maa ṣe lilo ere idaraya lati ṣe afọmọ ara wa''

Olori igbimọ to n risi ọrọ idije Olympic ati Olympic awọn to ni ipenija kan tabi omirna Ọmọ ọba Abdulaziz bin Turki bin Faisal sọ pe ''idije bọọlu agbaye jẹ afojusun pataki ninu irinajo Saudi gẹgẹ bi orileede to nifẹ si ere bọọlu.''

Australia, tohun ti pe igbimọ ere bọọlu Asian Football Confederation (AFC) jẹjẹ atilẹyin fun Saudi sọ pe awọn naa yoo sagbeyẹwo bi awọn yoo ṣe gbalejo idije 2034.