Luis Rubiales àti Jenni Hermoso: Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìfẹnukonu tó dá wàhálà sílẹ̀ lágbo eré bọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ní Spain

Rubiales fi fẹ ẹnu ko Hermoso lẹnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ ajọ bọọlu Spain, Luis Rubiales, ifẹnukoẹnu pẹlu agbabọọlu obinrin, Jenni Hermoso lasiko ti wọn gba ami ẹyẹ ni bi aṣekagba idije ife ẹyẹ agbaye ni Australia.

Akoko yii lo yẹ ko jẹ asiko ajọyọ fun ere bọọlu obinrin lorilẹede Spain, Igba akọkọ ti wọn yoo gba ife ẹyẹ agbaye fun ikọ agbabọọlu obinrin sugbọn ki lo sẹlẹ lasiko ajọyọ lẹyin ti Spain fi idi England janlẹ ni asekagba idije naa ni Australia gba ọna miiran yọ, to da ọpọlọpọ wahala silẹ.

Ihuwasi Luis Rubiales, Aarẹ ere bọọlu ti wọn fofin de da ọpọlopọ rogbodiyan silẹ laarin awọn ololufẹ ere bọọlu nigba ti wọn rii to fi ẹnu ko ẹnu pẹlu agbabọọlu obinrin Jenni Hermoso nigba to n fun wọn fi ami ẹyẹ naa.

Bakan naa ni wọn rii nibi to ti di nnkan ọmọkunrin rẹ mu nibi aye awọn eeyan pataki ki ifẹsẹwọnsẹ to pari.

Ifẹnukoẹnu yii ati ihuwasi rẹ nibi aye awọn eeyan pataki to joko si ti da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ lagbo ere bọọlu ni Spain.

Eyi ni ibeere mẹta lati fi oye kikun han nipa nnkan to sẹlẹ:

1. Ki ni Luis Rubiales ṣe?

Jenni Hermoso fẹnukoẹnu kan ami ẹyẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Hermoso jẹ ko di mimọ pe oun ko fẹran ifẹnukoẹnu naa

Rubiales, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, darapọ mọ awọn to n wo ifẹsẹwọnsẹ naa nibi ti Spain ti fi iya jẹ England pẹlu ami ayo kan sodo lati aye awọn eeyan pataki ni papa isere Australia niluu Sydney.

Nigba ti fere pe ifẹsẹwọnsẹ ti pari dun, Rubiales, ẹni to n duro lẹgbẹ Olori Letiza ti orilẹede Spain ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, Infanta Soffa gba nnkan ọmọkunrin rẹ mu lasiko to n ṣe ajọyọ.

Nigba to ya lasiko ti wọn gbe ami ẹyẹ fun awọn agbabọọlu, ifẹnukẹnu pẹlu Hermoso, ẹni to gba bọọlu fun ikọ Pachuca lorilẹede Mexico, waye.

Lasiko to n kii ku oriire, Rubiales gba Hermoso lori mu pẹlu ọwọ rẹ mejeeji, to si fi ẹnu ko o lẹnu.

Hermoso bọ sori ayelujara lati bu ẹnu atẹ lu iwa yii, to si ni oun ko nifẹ sii rara.

Rubiales kọkọ tọrọ aforijin fun iwa rẹ ṣugbọn aṣoju aarẹ orilẹede Spain, Pedro Sanchez ati aṣoju minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Yolanda Diaz ni titọrọ aforijin ko to, ti wọn si pe fun pe ko kọ iwe fi ipo rẹ silẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹede Spain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awuyewuye bẹsilẹ lasiko ti wọn ṣe ajọyọ pe wọn gba ife ẹyẹ agbaye.

2.Bawo ni ifẹnukoẹnu Luis Rubiales/Jenni Hermoso ṣe da wahala silẹ lagbo ere bọọlu?

L'Ọjọbọ, Ajọ FIFA kede pe awọn ti gbimọ kalẹ lati ṣe iwadi lori ẹsun ti wọn fi kan Rubiales.

Lọjọ keji, Ajọ RFEF pe ipade nibi ti wọn ti reti pe ki Rubiales kọwe fipo silẹ ṣugbọn o kọ jalẹ, o ni oun ko ni kọwe fipo silẹ.

Rubiales tọrọ aforijin pe o di nnkan ọmọkunrin rẹ mu ṣugbọn o ṣe ileri pe oun yoo ja nitori ifẹnukoẹnu to waye ko ki n ṣe nnkan babraa ati pe ajọmọ ni.

Ṣugbọn lọjọ naa, Hermoso ni ifẹnukoẹnu naa ki ṣe ajọmọ ati pe oun ko nifẹ sii rara. Ijọba orilẹede Spain ti bẹrẹ igbesẹ lati fofin de Rubiales gẹgẹ bi akọwe ijọba ṣe sọ.

Lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, Ajọ Fifa kede pe awọn ti fofin de Rubiales titi iwadi yoo fi pari.

Awọn agbabọọlu lati ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Spain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Spain gba ife ẹyẹ agbaye akọkọ to waye ni lorilẹede Australia ati New Zealand

3. Luis Rubiales ati ijọba orilẹede Spain: Ki ni yoo sẹlẹ bayii?

Lẹyin ikede lati gbe Rubiales lọ ileẹjọ ati ifofin de latọdọ Ajọ FIFA, ero awọn amoye nipa ere bọọlu ati ileẹjọ nipa ere idaraya lo ku.

Ti wọn ba pinnu lati bẹrẹ iwadi to tako Rubiales, eyi le fa ki wọn le e kuro.

FIFA ti pa a laṣẹ fun Rubiales ati aṣoju RFEF kankan lati ma kan si Hermoso, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

Pedro Rocha Junco, amugbalẹgbẹ Rubiales ati igbakeji aarẹ ajọ ere bọọlu, ni wọn fi jẹ olori igbimọ to n ṣe iwadi lori ẹsun ti wọn fi kan Rubiales .