Ìwádìí BBC nípa àjọ bọ́ọ̀lù Gabon níbi tí àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá ti ń fipá bá àwọn ọ̀dọ́ agbábọ́ọ̀lù láṣepọ̀

Àkọlé fídíò, àwọn akọ́ninipágbá ní Gabon ń fipá bá àwọn ọ̀dọ́ agbábọ́ọ̀lù láṣepọ̀

Ẹkun etikun gusu Afirika ni orilẹede Gabon sọlẹ si. Iditẹgbajọba to waye lorilẹede naa laipẹ yii mu ki o tun gbajumọ lawujọ orilẹede agbaye.

Amọṣa, yatọ si iditẹ gbajọba yii, iwa ibajẹ kan n waye labẹnu ti ko han si araye lorilẹede naa –

Gbogbo ọdọ lorilẹede Gabon lo ni ala rere lati di agbabọọlu to lorukọ ti yoo si lee ṣoju orilẹede naa lawọn idije agbaye gbogbo.

Lọdun mẹrin sẹyin, ọkan lara awọn odu agbabọọlu orilẹede naa, Parfait N’dong pada wa si orilẹede naa lati da ileẹkọ nipa bọọlu gbaigba silẹ.

“Mo ni ifẹ lati pada wa si Gabọn. Ero mi si ni pe awọn nnkan ti mo nkọ awọn ọmọde loke okun ki n wa kọ awọn ti orilẹede mi gan an ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ọdun loke okun, mi o mọ pe nnkan ko ri bi mo ti fi silẹ nile mọ ni Gabon.”

Ki lohun toju Oafait ri nigba to pada si ile?

Aworan ọmọ kan ninu ile

Oríṣun àwòrán, bbc

Nigba ti yoo fi pada sile, iwa fifi awọn ọdọkunrin agbabọọlu ṣe ibalopọ ti wa di tọrọfọnkale nibẹ.

O ni gbogbo awọn adari ere bọọlu lorilẹede naa lohun ti ba sọr lori aṣa buruku yii ṣugbọn ti ko si ẹni to fẹ tẹti gbọ ohun to n sọ.

BBC ba awọn ẹlẹri to le ni ọgbọn sọrọ, gbogbo wọn lo si fi idi rẹmulẹ pe aṣa buruku biba awọn ọmọ to wa lati gba bọọlu di ọlọla ni ibalopọ ti gbilẹ fun pọlọpọ ọdun.

Awọn ẹlẹri naa ni ajọ ere bọọlu lorilẹede naa, Fegafoot m si iwa buruku naa.

Nigba ti iwe iroyin kan lorilẹede Gẹẹsi tu aṣiri iwa buruku yii sita lọdun 2021 ni awọn alaṣẹ to fi panpẹ ofin gbe awọn aknimọọgba mẹrin.

Mẹta ninu wọn lo ṣi wa ni ọgba ẹwọn bayii.

Koda ọkan lara wọn tilẹ jẹwọ pe oun maa n fi ipa ba awọn ọdọkunrin agbabọọlu ni ibalopọ akọsiakọ nibẹ.