Iléeṣẹ́ reluwé Nàìjíríà jáwe lọ rọọ́kún nílé fún àwọn òṣìṣẹ́ tó gba owó lọ́wọ́ èrò ọkọ̀ dípò tíkẹ́ẹ̀tì

NRC

Oríṣun àwòrán, Journalist KC

Ileeṣẹ to n ri irinna ọkọ oju irin ni Naijiria, NRC, ti jawe lọ rọokun nile fun awọn oṣiṣẹ rẹ kan ti wọn gba owo lọwọ ero ọkọ oju irin kan lati ilu Ibadan si Eko, kaka ki wọn fun ta tikẹẹti ijọba fun wọn.

Ṣaaju ni fidio idunadura laarin awọn oṣiṣẹ NRC naa atawọn ero ọkọ ti ọrọ kan ti kọkọ gbode lori ikanni X, lẹyin ti ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọrọ soke.

Lẹyin ti fidio aṣemaṣe awọn oṣiṣẹ naa fa oju opo X ya ni ileeṣẹ ọhun ṣeleri lati da seria fun awọn oṣiṣẹ rẹ to ṣe aṣemaṣe.

Ninu atẹjade kan ti igbakeji agbẹnusọ NRC, Yakub Mahmood, fi lede lo ti kede pe ki awọn oṣiṣẹ ti ọrọ naa kan lọ rọọkun nile fun igba diẹ titi ti iwadii awọn lori ọhun to ṣẹlẹ yoo fi pari.

NRC

Oríṣun àwòrán, NRC

Mahmood ni “A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe ileeṣẹ NRC koro oju si iwa aibọwọ fun ofin ati alakalẹ ti awọn oṣiṣẹ naa wu, paapaa lasiko yii ti ijọba apapọ n tiraka lati tun ileeṣẹ naa ṣe.”

“Iwa ti wọn wu ba wa ninu jẹ, ko bojumu bẹẹ ni ko ṣe itẹwọgba nitori o lodi si alakalẹ ileeṣẹ wa.”

“Nitori naa, ileeṣẹ wa ti jawe lọ rọọkun nile fun awọn oṣiṣẹ ti oje ọrọ naa ṣi mọ lori titi ti esi iwadii to n lọ lọwọ yoo fi jade.”

“A fẹ fi da awọn onibara wa ati gbogbo araalu loju pe a ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ yii, ati pe eyikeyi oṣiṣẹ wa to ba mu ẹrẹ ba orukọ ileeṣẹ wa ko ni lọ lai jiya to tọ.”

NRC sọ siwaju si pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ibajẹ naa ni awọn yoo fi imu wọn danrin.

Lẹyin naa lo ke si awọn araalu lati maṣe fun ẹnikẹni ni owo ọkọ oju irin, kaka bẹẹ, ki wọn maa bere tikẹẹti lọwọ awọn oṣiṣẹ awọn.

Mahmood fi kun pe awọn eeyan yoo le maa ra tikẹẹti naa funra wo lori ayelujara titi opin oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii.