School reoppening date: Ìjọ́ba ìpínlẹ̀ Kwara kéde pé ki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé wọlé padà

Gomina ipinlẹ Kwara ati awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, @RealAARahman/TOLU OGUNLESE

Ìjọba Kwara kéde ọjọ iwọlé àwọn akẹkọọ lẹyìn ìséde Covid 19!

Ijọ́ba ipinlẹ Kwara ti ni ki awọn akẹkọọ ile iwe alakọbẹrẹ ati girama wọle pada lọjọ Aje to m bọ.

Ijaba kede pe awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ọpọlọpọ ipade ati iforikori lori ati wa ọna ti ajakalẹ arun coronavirus ko fi ni maa tan kalẹ ti awọn akẹkọọ ba wọle sile iwe.

Koda, wọn ni ijọba ti seto awon ọna ikọni fun awọn Olukọ

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Kwara ni : a sẹsẹ fi ẹnu ọrọ ko pe ki awọn akẹkọọ wẹle pada sile iwe wọn.

Ọjọ karun un, osu kẹwaa, ọdun 2020 ni awọn akẹkọọ naa yoo apda si kilaasi nile iwe girama ati alakọbẹrẹ

Nigba ti awọn ti ile iwe giga ti ipinlẹ Kwara yoo wọlè pada lọjọ ti awọn adari ile iwe kọọkan ba gba pe asiko to bẹrẹ lati ọjọ kejila, osu kẹwaa, ọdun 2020.

Imọran ijọba ipinlẹ Kwara ni pe ajakalẹ arun coronavirus si wa pẹlu wa fun idi eyi ki gbogbo Olukọ ati awọn eeyan maa tẹlẹ ilana ajọ WHO bi o ti yẹ ki ọkan koowa le balẹ