Yoruba Nation kọ́ ló pa Jumoke l‘Ojota, Ọlọ́pàá ni - Ìgbìmọ̀ olùwádìí
‘’Ẹ fi ojú ọlọ́pàá tó pa Jumoke lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation Eko hàn’’

Iwadii lori ohun to ṣekupa Jumoke Oyedele lasiko iwọde Yoruba Nation nilu Eko, ti fi ẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn jẹbi lori iku rẹ.
Iwadii ọhun safihan pe awọn ọlọpaa lo pa Jumoke to n kiri ọja ni agbegbe Ọjọta lasiko iwọde naa.
Asaaju ikọ to se iwadii iku obinrin naa, Maikaila Fadeyi to fi ero rẹ han ni ileẹjọ Samuel Ilori Courthouse, ni Ogba ni ilu Eko, sọ ohun ti iwadii gbe jade.
Adajọ koro oro si aibikita ileeṣẹ ọlọpaa si iku Jumoke
Fadeyi ni iwadii oniruuru ti wọn ṣe lori iku Jumoke to waye ni Ọjọ Kẹta, Osu Keje, ọdun 2021 fihan pe ibọn ti ọlọpaa Naijiria yin lu obinrin naa lo ṣekupa a.
Adajọ Magisireti wa fi aidunnu rẹ han si aibita ikọ ileeṣẹ ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa lasiko igbẹjọ, ti wọn ko tilẹ bu iyi fun ileẹjọ.
Magisreti naa to ba ẹbi Jumoke kẹdun ni ọmọbinrin ọdun marundinlọgbọn naa ni erongba lati ṣe rere laye, ki o di eniyan nla.
Amọ eyi ko ṣeeṣe nitori ileeṣẹ ọlọpaa gbẹmi ọdọbinrin naa ni aipe ọjọ.
Iroyin ni agbẹjọro ijọba, Seun Akinde yọju si ileẹjọ amọ wọn ko ri agbẹjọro ileeṣẹ ọlọpaa.
''Irọ ni pe ọlọpaa ko yin ibọn kankan ni iwọde Yoruba Nation''
Iwadii ti ileewosan se lori oku Jumoke naa fihan pe awọn ọlọpaa lo yinbọn pa nibi iwọde naa.
Lẹyin ti awọn ọlọpaa kọ jalẹ pe awọn ko yin ibọn ẹyọ kan ṣoṣo nibi ti awọn ti dẹkun iwọde wọn ọhun.
Iwadii ileewosan to bẹrẹ ni Osu Kẹjọ, ọdun to kọja gbọ ọrọ lẹnu iya Jumoke, igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa ati onimọ nipa iwadii nipa oku lati ileewosan LASUTH naa wa nibẹ.
Bakan naa ni oṣojumikoro kan sọ fun ileẹjọ pe awọn ọlọpaa kan tun bẹrẹ si ni yẹ gbogbo ara obinrin naa wo lẹyin ti oku rẹ wa nilẹ.
Magisreti naa wa ke si ijọba apapọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ wa awọn oṣiṣẹ wọn, to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa jade, ki wọn si foju wina ofin.
Adajọ naa ni o yẹ ki ijọba bẹrẹ si se ayẹwo ọpọlọ fun ọlọpaa kọọkan lati mọ boya ọpọlọ osisẹ naa pe to lati gbe ibọn.
O tun rọ ijọba lati gbe igbeṣẹ nipa lila awọn ọlọpaa ni oye nipa ̣ẹtọ awọn araalu lati fi ẹhọnu wọn han lai ṣe pe wọn doju ija kọ wọn.















