Wọ́n rẹ ọrùn ọmọ ọdun méjìlá, gbé òkú rẹ̀ sín àpótí

Lola

Oríṣun àwòrán, Facebook

 Awọn alaṣẹ ni France ti bẹrẹ si n ṣe iwadii iku akẹkọbinrin ọmọ ọdun mejila kan ti wọn ba oku rẹ ninu apoti niluu Paris, lorilẹede France.

Ọmọdebinrin ọhun, ti orukẹ rẹ n jẹ Lola, ni wọn sọ pe o maa n lo gbogbo akoko rẹ nile ẹkọ rẹ.

Baba ọmọ naa lo kọkọ ke sita lẹyin ti ọmọ ọhun ko pada sile lasiko to ṣaba maa n dele.

Alẹ ọjọ kan naa ni wọn ṣawari oku ọmọ naa ninu apoti ni ori orule ile wọn.

Nigba ti wọn ri oku rẹ, wọn ba ti wọn de apa ati ẹsẹ rẹ, ti wọn si ri apa ibi ti wọn ti rẹ ọrun rẹ.

Ọwọ tẹ awọn afurasi lori iku Lola

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ṣikun ofin mu ẹni ti wọn fura si pe o pa ọmọ naa, iyẹn obinrin ọmọ orilẹ-ede Algeria kan, Dahbia B.

Wọn mu obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun naa lẹyin ti wọn ri ninu aworan CCTV pẹlu oloogbe ọhun, wọn si ni oun ni wọn ri kẹyin pẹlu rẹ, ki wọn to ri oku rẹ.

Iroyin ni wọn ri to n fi ile awọn obi ọmọ naa silẹ pẹlu apo kan lọwọ rẹ, to si n rin irin ifura laarin adugbo.

Amọ awọn ọlọpaa ti ni o ṣeeṣe ki obinrin naa ma mọ nnkankan nipa iku ọmọ ọhun nitori pe ko ni ile to n gbe, bẹẹ si ni o ni arun ọpọlọ.

Ọlọpaa tun ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan ti wọn gbagbọ pe oun lo fi ọkọ rẹ gbe Dhabia B ati apo ti wọn gbe oku ọmọ naa si ninu ọkọ rẹ.

Iyawo Aarẹ orilẹ-ede naa, Brigitte Macro ti bu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o si sajuwe rẹ gẹgẹ bii eyii to buru jai.