Ẹ fura o! Àjọ NAFDAC ké gbàjarè lórí ayédèrú òògùn Augmentin

Oríṣun àwòrán, nafdac
Ajọ to n mojuto lilo ati tita oogun ati ounjẹ ni NAFDAC, ti kede pe awọn ti kẹẹfin ayederu oogun onikoro, Augmentin 625mg, ti awọm kan n ta kiri Naijiria bayii.
Ninu atẹjade to fi si ori ayelujara Twiiter rẹ ni ọjọ Aiku, NAFDAC sọ pe ayederu oogun naa ko ni awọn amuyẹ to yẹ ko ni.
- Awọ ara rẹ yatọ si ti ojulowo
- Ko si orukọ ileeṣẹ to ṣe e lara, afi adirẹsi nikan
- Wọn o kọ ọjọ ti wọn ṣe e ati igba ti ọjọ yoo lọ lori rẹ (expiry date) ni ilana to yẹ
- Ayederu oogun naa ko ni nọmba MAS, ti eeyna le fi mọ pe ojulowo ni
- Ami idanimọ ileeṣẹ GSK to n ṣe oogun naa, ko si ni ibi to ma n wa lara paali ojulowo
Bakan naa ni ajọ naa sọ pe gbogbo akọsilẹ to wa lara oogun naa lo fihan pe ayederu ni.
Awọn nkan mii to yẹ ki o kiyesi lara ayederu oogun Augmentin

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
- Orukọ oogun naa ni Augmentine 625mg
- Nọmba ara rẹ (Batch Number): 562626
- Ọjọ ti wọn ṣe e : Oṣu Kẹrin, ọdun 2021
- Nọmba NAFDAC: 04-1928
Ajọ NAFDAC ti wa kilọ̀ fun awọn alagbata ati awọn ile itaja oogun oyinbo, lati ri i daju pe wọn n ra awọn oogun wọn lọwọ awọn alagbata n la to ni aṣẹ ati ontẹ. Ki wọn o si ma a sẹ ayẹwo awọn oogun ti wọn ba ra finni-finni.
Bakan naa ni ajọ naa tun gba awọn ileewosan ni imọran pe ki wọn o ma a yẹ oogun wo daadaa, ki wọn o to o fun awọn alaisan.
Ọjọ diẹ sẹyin ni NAFDAC gbẹsẹ le oogun onikoro Dexamethasone ti wọn ri nipinlẹ Anambra, nitori pe ko poju owo.
Wọn gbẹsẹ le oogun naa, wọn si ni ki awọn ile itaja to ba ni lọwọ da wọn pada nitori pe ayẹwo fihan pe odinwọn awọn eroja inu rẹ kere ju iye ti wọn kọ si ara iwe ti wọn lẹ mọ lara.
Bakan naa ni wọn ni oogun naa ni eroja methylparaben ati propylparaben, diẹ ninu.
Awọn eroja yii ni wọn fi n ṣe nkan lọ́jọ̀, ko le wa fun ọjọ pipẹ lai bajẹ.
NAFDAC sọ pe oogun naa ko nilo rẹ rara.
Laipẹ yii ni ajọ naa tun ke gbare lori bi awọn ipara ati ọṣẹ ibora ṣe di tọ́rọ́ fọn kale ni Naijiria.
Eyi ti wọn lo mu ki arun jẹjẹrẹ pọ̀ si kaakiri ni Naijiria.
Nafdac wa di ẹbi isẹlẹ naa ru awọn olookowo to n pese ipara to n bo ara fawọn aralu lọna to lodi sofin.Ajọ naa ni ọpọ eroja majele fun agọ ara lawọn onisowo ibora naa n po papọ, eyi to le se ijamba fun awọ ara lode ati ninu.












