Afurasí Ajínigbé wa ẹkún mu bíi bèbí nígbà tó kó sọ́wọ́ Amotekun n‘Ibadan
Afurasí ajínigbé ní láti Eko lawọn ti ń ṣọ́ àwọn èèyàn tawọn fẹ́ jí gbé wá sí Ibadan

Oríṣun àwòrán, sojworldnews
Ikọ Amotekun ipinlẹ Oyo ti fi ṣikun ofin mu afurasi ajinigbe kan, Sunday Oja.
Iroyin ni afurasi naa wa lara awọn ajinigbe to ji ọkunrin kan, Arogundade Sunday gbe lagbegbe Temidire, nitosi ọja Eleekara nilu Oyo, nipinlẹ Oyo.
N ṣe ni afurasi naa, to sọ pe ọmọ ipinlẹ Benue ni oun, n sunkun bi ọmọ ọwọ lẹyin ti ọwọ Amotekun tẹ ẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati ilu Eko ni wọn ti n ṣọ tabi tọpasẹ awọn eeyan ti wọn ji gbe wa si Ibadan, ki wọn to ṣọṣẹ.
Eko la ti maa n sọ awọn eeyan ta ba fẹ ji gbe wa si Ibadan - Afurasi Ajinigbe
O tun sọ pe ilẹ ti ta si ti oun ti n ṣiṣẹ ajinigbe naa.
Nigba ti Amotekun n fi ọrọ wa lẹnu wo ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan, afurasi ajinigbe naa ni ẹnu lọọlọ yii ni oun ati awọn ẹmẹwa oun ji eeyan meji gbe.
O ni “Lati oju irin Ikeja, niluu Eko ni a ti n ṣọ wọn bọ... ẹjọ ẹ ṣaanu fun mi.”
Afurasi naa tun darukọ afurasi mii to pe orukọ rẹ ni Damilola ati olori ikọ rẹ, eyii to pe ni Jagaban to n fi agbegbe Ikeja ṣebugbe, niluu Eko.
Asiko ti mọto mi taku, ni awọn afurasi naa ji mi gbe - Arogundade Sunday
Ọkunrin kan ti afurasi naa atawọn ẹmẹwa rẹ ji gbe, Arogundade Victor Sunday ṣalaye fun ikọ Amotekun pe asiko ti ọkọ oun taku loju ọna ni wọn ji oun gbe.
Ọkunrin naa ni “Ọjọ Satide ni mo kuro l’Eko, ti mo n lọ siluu Kano, awa mẹta ni.”
“Nigba to ku kilomita mẹwaa ki a de ilu Oyo, ni ọkan ninu awọn mọto ti a n gbe lọ ko sinu koko kan ti a n si n wa ọna lati gbe jade.”
“Bi a ṣe gbe jade tan naa ni mọto Venza temi gan taku, ibi ti mo ti n pe mẹkaliiki ni wọn ti yọ si mi.”
“Wọ le mi, mo ṣare, mo ja sinu koto sibẹ ni ṣe ni wọn n le mi.”
Ọgbẹni Sunday sọ pe awọn ajinigbe naa fi okun de ọwọ oun lẹyin ti wọn ji oun gbe tan ki ikọ Amotekun to doola oun.















