Àdó olóró méjì tó dún léraléra gbẹ̀mí èèyàn 100 ní Somalia

Somalia Mogadishu bombings

Oríṣun àwòrán, AFP

    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, Akọroyin BBC

O kere tan, ọgọrun eeyan lo jade laye, nigba ti ọọdunrun mii farapa lẹyin ti ado oloro meji bu gbamu leralera niluu Mogadishu, ni Somalia.

Aarẹ orilẹ-ede naa, Hassan Sheikh Mohamud ti ke si awọn orillẹ-ede agbaye lati fi ohun iranwọ ranṣẹ lọna ati tọju awọn to farapa ninu ikọlu naa.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe awọn iya ati ọmọ wọn wa lara awọn eeyan to ba ibugbamu naa lọ ladugbo kan ti ọpọ ero ma n wa nilu n pọ si.

Sheikh Mohamud ti di ẹbi ikọlu naa le ẹgbẹ agbesumọmi al-Shaba lori.

Somalia Mogadishu bombings

Oríṣun àwòrán, Reuters

Al-Shabab lo wa nidi ikọlu naa

Ẹwẹ, Al-Shabab ti sọ loju opo wọn lori ayelujara pe awọn lo wa nidi ikọlu naa ti wọn ṣe si ọọfisi ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti al-Shabab, to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ikọ agbesumọmi al-Qaeda, yoo gbena woju ẹkun ijọba Somalia.

Ṣaaju ni Aarẹ Mohamud, to gba ijọba loṣu marun un ṣeyin, ti kọkọ ṣeleri pe oun yoo gbogun ti ẹgbẹ agbesunmọmi naa, iyẹn lẹyin ti wọn kọlu ile itura kan, nibi ti wọn ti gbẹmi eeyan mọkanlelogun.

Ibugbamu ti opin ọsẹ yii waye lerelera laarin iṣẹju diẹ sira wọn, eyii to ba ile, ọkọ atawọn dukia mi jẹ.

Bi ikọlu ọhun ṣe waye ree:

Ibugbamu akọkọ ba ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ jẹ, nigba ti ibugbamu keji waye ni kete ti awọn adoola ẹmi de ibi ti ibugbamu akọkọ ti waye.

Nnkan bi ọdun marun sẹyin ni ọkọ ajagbe kan bu gbamu ni agbegbe yi kan naa, ninu eyii ti ẹmi ẹẹdẹgbẹta eeyan ti sọnu.

Ikọlu ti ọdun karun un naa ni wọn sọ pe o buru julọ ninu itan Somalia.

Wayi o, ogunlọgọ araalu lo ti korajọ si ibi ti ikọlu naa ti waye bayii lati wa awọn mọlẹbi wọn to ṣeeṣe ko wa nibẹ.

Lara awọn to ba ikọlu tuntun yii lọ ni gbajugbaja akọroyin kan ati ọga ọlọpaa.